YO/Prabhupada 0089 - Itasan Krishna ni orisun gbogbo nkan
Lecture on BG 4.24 -- August 4, 1976, New Mayapur (French farm)
Olujosin Fransé: Kini o tumo si nigbati Krishna so wipe "Emi o si ninu won"?
Prabhupāda: Huh? "Emi o si ninu won" nitoripe e ko le ri nibe.. Olorun wa nbe, sugbun e ko le Ri. E o ti ni itesiwaju. Gege bi apeere miran. Nibi yi, imole oorun wa nibi. Gbogbo enyan ni oni iriri yi. Sugbon iyen o tumo si wipe oorun wa nibi. Se o daju? Oorun wa nibi a tumo si wipe... Imole oorun wa nibi tumo si wipe oorun wa nibi. Sugbon sibe, ntoripe e wa ninu itansan oorun e ko le so wipe "Emi ti ri oorun mu." Imole wa ninu oorun, sugbon oorun fun ra re ko si ninu itansan oorun. Laisi oorun ko le si itansan oorun. Iyen ko nse wipe itansan oorun ni oorun. Ni ohun kan na, e le so wipe itansan oorun ni oorun.
Eyi ni a npe ni acintya-bhedābheda, isekan nigbakanna ti o tun yato. Ninu itansan oorun é o lero niwaju oorun, sugbon ti e ba ni anfaani lati te si nu agbaye oorun, e tun le pade oludari-oorun na. Nitooto, imole oorun na tumo si itansan ara eni ti o ngbe ninu agbaye oorun. Ti o ti wa ni alaaye ninu Brahma-samhitaa, yasya prabhā prabhavato jagad-aṇḍa-koṭi (Bs. 5.40). Lori akoto ti Krishna... E ti ri itansan Krishna ti o mbo. Iyen ni orisun gbogbo nkan. Ti imugborosi itansan na ni brahmajyoti, ati ninu brahmajyoti, awon aye-orun emi ailonka, awon aye ohun-elo, ni won gbejade. Ati ninu ikookan ati gbogbo aye-orun ni orisirisi awon nkan se gbejade. Ni gangan, itansan ara Olorun ni ipilese na, ati ipilese itansan yi ni Olorun.