YO/Prabhupada 0093 - Bhagavad-gita tun je Krishna



Lecture on Brahma-samhita, Lecture -- Bombay, January 3, 1973

Bee na Srimad- Bhagavatam ni alaaye atilewa ti Vedanta-sutra. Bee na ninu Vedanta-sutra, alaaye Vedanta-sutra, Srimad Bhagavatam, o so wipe,

janmādy asya yataḥ anvayāt itarataś ca artheṣu abhijñaḥ
tene brahma hṛdā ādi-kavaye muhyanti yatra sūrayaḥ
(SB 1.1.1)

Awon apejuwe wonyi wa nibe. Bee ni aadi-kavi, aadi-kavi tumo si Brahman. Brahma, Adi-kavi. Bee na ni brahma. Brahma tumo si sabda-brahma, iwe Vediki. Bee na Lo se ko leko tabi fun ni imoran lati okan Brahmaa. Nitori nigba akoda-aseda wa nbe, Brahma nikan ni eda alaaye, ni ibeere aye. Bee na a le se ni ibeere pe "Bawo ni Brahmaa se ko eko Vediki?" Ti o wa ni alaye: tene brahma... Brahma tumo si iwe Vediki. Sabda-brahman. Alaye na, apejuwe Olorun na ni Brahman. Brahman ni atobiju. Ko si iyato larin Brahman ati iwe ti o ns'apejuwe Brahman. Bakanna: gege bi Bhagavad Gita ati Krishna, ko si iyato. Bhagavad Gita tun je Krishna. Bibeko kilode ti won se nsin iwe yi, niwon, lati igba pipè, lati egberun marun odun, ayafi ti Bhagavad Gita ni Olorun? Awon opolopo iwe ni won wa, awon iwe, ti won wa ni atejade lasiko yi. Leyin odun kan, odun meji, odun meta - o pari. Ko s'eni to tun fe won mo. Ko s'eni to ni fe si. Ko s'eni to ka kun... Iwe k'iwe ti a le mu ninu itan aye, ko si iwe itan na ti o le se egberun odun marun, ti o si nje kika lera lera fun opolopo awon omowe, awon elesin ati awon ojogbon, gbogbo. Kilo fa? Nitoripe o je Krishna. Krishna... Ko si iyato laarin Bhagavad Gita ati Bhagavan. Sabda-brahman. Fun bee na, ko ye ki a mu Bhagavad Gita gege bi iwe lasan. ti a kan le se oroiwoye si lori nipa ti imo a l'A B D. Rara o.. Iyen ko see se. Awon omugo ati awon alaibikita, won gbiyanju lati se alaye l'ori Bhagavad Gita, nipa imo a l'ABD won. Iyen ko see se. Sabda-brahman. O ma je afihan fun eni ti o ba ni ifokansin fun Krishna. Yasya deve para bhaktir yatha deve... Awon imoran Vediki ni won yi.

yasya deve parā bhaktir
yathā deve tathā gurau
tasyaite kathitā hy arthāḥ
prakāśante mahātmanaḥ
(ŚU 6.23)

Won ti di afihan. Nitorina a npe awon iwe Vediki ni afihan. Ki se nipa imo a l'ABD yin ni mo le ni oye nipa re. Mo le ra Bhagavad Gita, ati nitoripe wipe mo ni imo iwe, o le ye mi. Rara o. Vedesu durlabha. Ninu Brahma-samhita o ti wa ni wipe, vedesu durlabha E ma se eko iwe Vediki lo nipa agbara imo yin - durlabha. Iyen ko see se. Vedesu durlabha. Nitorina opolopo eniyan lo wa, ti won nse igbiyanju lati se ogbufo Bhagavad Gita nipa imo karohun-wi sikolashipu won. sugbon ko s'eni to nse aniyan won. Won o tile le yi enikan pada ko di olufokansin Olorun. Eyi je ifowo soya. Ni ilu Bombay yin opolopo eniyan wa nbe, ti wo nse alaaye Bhagavad Gita lati awon opo odun, sugbon won o le yi enikan soso pada si olufokansin mimo Olorun. Eyi ni ifowo soya wa. Sugbon Bhagavad Gita yi, bayi o ti wa ni alaaye gege bi o ti je, ati wipe awon egbe gberun awon Oyinbo ati awon ara ilu Okeere Amerika, ti awon baba-baba won tabi iran won kan o mo oruko Olorun si Krishna, ti won si ndi olufokansin. Eyi ni asiri aseyori. Sugbo awon omugo eniyan won yi, ko ye won. Won ro wipe bi won ba nse ogbufo Bhagavad Gita nipa karohunwi alaibikita imo won, awon le se ifihan Bhagavad Gita. Iyen ko see se. Nāhaṁ prakāśaḥ yogamāyā-samāvṛtaḥ. Olorun ki fara han fun awon omugo ati awon alaibikita. Olorun ki fi are Re han. Nāhaṁ prakāśaḥ sarvasya (BG 7.25). Oun ki se ohun ti o j'opo pupo ti O ma je agboye fun awon omugo ati awon alaibikita. Ko see se. Olorun so wipe, nāhaṁ prakāśaḥ sarvasya yogamāyā-samā... (BG 7.25).

manuṣyāṇāṁ sahasreṣu
kaścid yatati siddhaye
yatatām api siddhānāṁ
kaścid vetti māṁ tattvataḥ
(BG 7.3)