YO/Prabhupada 0107 - E ma tun gba ara aye yi miran
Lecture on BG 4.17 -- Bombay, April 6, 1974
Kii se pataki boya ara ti oloro tabi ti talaka ni. Gbogbo eniyan ni o ni lati faragba awọn iya onílọọpo meta majemu aye yi. Nigbati ako-iba ba mu ni, ko nse iyato pe: "Eyi ni ara ọlọrọ. Emi a fun ni irora kekere." Rara o. Nigba ti ako-iba ba de, boya ara rẹ jẹ ti ọlọrọ tabi ara talakà , o ni lati jiya irora kanna. Nigbati o ba wa ninu iya rẹ, o ni lati jiya irora kanna, boya o wa ninu ayaba tabi ninu aya akobata. Ipo to ro ni lowo-lese po.... Sugbon awon eniyan o mo.... Janma-mṛtyu-jarā. Ijiya to po lowa nibe. Ninu ibimo Opolopo iya lo wa ninu ise ibimo, iku ati ni idarugbo. Olọrọ ọkunrin tabi talakà eniyan, nigba ti a ba di arugbo, a ni lati jìya ọpọlọpọ awọn irora.
Bakanna, janma-mṛtyu-jarā-vyādhi (BG 13.9). Jarā, jarā ati vyādhi ati mṛtyu. Be ni a wa ko mọ nipa awọn ipo ti ijiya ti ara aye yi. Awon iwe mimo so wipe: "E ma tun gba ara aye yi miran" Na sādhu manye: " Eleyi ko dara, pe e tun gba ara aye miran lera-lera." Na sādhu manye yata ātmanaḥ. Ātmanaḥ, emi-okan wa ninu ewon ninu ara aye yi. Yata ātmano 'yam asann api. Biotilejepe fun igba die, mo ti ni ara yi. Kleśada āsa dehaḥ.
Nítorí náà ti a ba fẹ da majemu iya ti gbigba ara aye miiran duro, a gbodo mo ohun ti a npe ni karma, ohun ti won pe ni vikarma. Imoran Olorun ni yI. Karmaṇo hy api boddhavyaṁ boddhavyaṁ ca vikarmaṇaḥ. Akarmaṇaś ca boddhavyam Akarmaṇa tumosi wipe kosi èsan. Esan. Karma, ti o ba ṣe iṣẹ to dara, o ti ni esan. O ni ara to dara, eko to dara, ebi to dara, ọrọ dara dara. Eleyi na tun dara. A ya bi o dara. A fẹ lọ si awọn ọrun aye . Sugobn won o mope awon orun aye paapa janma-mṛtyu-jarā-vyādhi wa nbe.
Nitorina Olorun ko fi seduro pe ki e losi orun ti ara. O so wipe ā-brahma-bhuvanāl lokāḥ punar āvartino 'rjuna BG 8.16) Bi e ba ti e lo si Brahmaloka, sibe na atunwa aye ati... Yad gatvā na nivartante tad dhāma paramaṁ mama (BG 15.6). Yad gatvā na nivartante. Sugbon awa ko mo wipe dhama wa. Ti a ba le nipa ona kan tabi omiran, ti a ba le gbera wa ga lo si dhaama na lehin na "na nivartante, yad gatvā na nivartante tad dhāma paramaṁ mama" Ni ibi miran wi pe, tyaktvā dehaṁ punar janma naiti mām eti (BG 4.9).
Be ni awon eniyan o ni alaye pe Krsna tabi Olorun Atobiju, O si ni ibi ti Re ati pe enikeni lo le lọ. Bawo la se le lọ?
- yānti deva-vratā devān
- pitṟn yānti pitṛ-vratāḥ
- bhūtāni yānti bhūtejyā
- yānti mad-yājino 'pi mām
- (BG 9.25)
"Ti eniyan ba ti ya isin Mi sọtọ, owo Mi, bhakti-yoga, yi o si wa si odo Mi." Ni ibi miran O so wipe, bhaktyā mām abhijānāti yāvān yaś cāsmi (BG 18.55).
Nitorina owo wa nikan ni lati ni oye Olorun.. Yajñārthe karma. Eyi ni akarma. O ti je si so nibi, akarmaṇa, akarmaṇaḥ api boddhavyam, akarmaṇaś ca boddhavyam. Akarma tumo si lai si esan. Nibi, ti a ba nsewa wu fun igbadun ara wa, esan re,... Gege ologun ti o npa yan. O si ngba ileke wura. Ologun kanna, ti o ba wa le, ti o si pa niyan, won ma fi pokunso. Kilode? O le sọ ni ile-ẹjọ, "Alàgbà, nigbati mo njà ni oju ogun, mo ti pa ọpọlọpọ. Mo si ni ileke wura. Kilode ti e fe fi mi pokunso nisinyi? "Nitoripe o ti ṣe fun igbadun ara rẹ. Ati wipe o ti se yen ni adehun ijoba."
Nitorina eyikeyi karma, ti e ba se fun itelorun Olorun, o je akarma. Ko si esan. Sugbon ti o ba se ohunkohun fun igbadun ara rẹ, iwo ni lati jiya igbese èsì, bi o dara tabi buburu. Nitorina Krsna so wipe,
- karmaṇo hy api boddhavyaṁ
- boddhavyaṁ ca vikarmaṇaḥ
- akarmaṇaś ca boddhavyaṁ
- gahanā karmaṇo gatiḥ
- (BG 4.17)
O wa ni soro gidigidi lati ni oye ohun iru igbese ti o yẹ ki o ṣe. Nitorina a ni lati gba itọsọna lati ọdọ Krishna, lati inu awọn shastra, lati ọdọ oluko. Nigbana ni aye wa yoo jẹ aseyori. E ṣeun pupọ. Hare Krishna.