YO/Prabhupada 0160 - Krishna ti soro soke



Conversation at Airport -- October 26, 1973, Bombay

Gege na egbe imoye Krsna wa yi fe ko awon eyan lati ni oye nipa iye aye. Eko aye isin ti baje tojepe awon eyan o mo nkan to je iye aye yi mo. Ni opolopo, ninu ile aye yi awon eyan ti gbagbe nkan toje iye aye, sugbon ati le mo bi ile-aye eda eniyan se je pataki, ni'di fun aye wa. Ninu Śrīmad-Bhāgavatam wan sowipe, parābhavas tāvad abodha-jāto yāvan na jijñāsata ātma-tattvam. Afi teyan ba laju si imoye imora eni, ounkooun ti awon eda yi base, ipadaseyin loma jefun. Ipadaseyin yi wa ninu aye awon eda to kere juwa lo bi awon eranko, nitoripe wan o mo itumo iye aye wa. Ogbon wan o fibe losiwaju. sugbon ti awon eda eniyan na bani awon ipadaseyin wanyi, awujo to da koniyen. Awujo awon eranko niyen. Āhāra-nidrā-bhaya-maithunaṁ ca samānyā etat paśubhir narāṇām. ti awon eyan o ba mo ju awon nkan merin aye yi - jijeun, sisun, imo ako ati abo ati igbeja ara - gbogbo awon nkan wanyi wa ninu ile aye awon eranko, kosi ilosiwaju kankan ninu iru awujo bayi. gege na ise tawan se ninu egbe imoye Krsna yi ni lati le mu awon eyan wa sori ipo tonle l'ogbon lati huwa bi eda eyan. Awujo Veda tawa niyen. Awon isoro aye yi ju awon isoro kekere taleni fun igba die tama wanbi. Isoro gidi tayeyi ni basele wa ona abayo si ibimo, iku, ojo arugbo ati aisan.

Ilana to wa ninu Bhagavad-gita niyen. Janma-mṛtyu-jarā-vyādhi-duḥkha-doṣānudarśanam (BG 13.9). awon tini idojuti pelu isoro to po gan laye yi, sugbon isoro gidi to wa ni basele fi ipari si ibimo, iku, ojo arugbo at'aisan. awon eyan si wa tio l'ogbon. Ori wan ti paana toje wipe kosi bonsele mo nkan to je isoro gidi laye yi. Ni aye atijo nigbati Viśvāmitra Muni ri Mahārāja Daśaratha, Mahārāja Daśaratha si beere lowo Viśvāmitra Muni, aihistaṁ yat taṁ punar janma jayaya: " Edakun Sa, mogbo pe afe ni idari lori Iku, bawo ni ise yi sen lo? Se kosi wahala lori oro na? Awujo Veda wa niyen, basele ni idari lori ibimo, iku, ojo arugbo ati aisan. Sugbon laye isin tawa yi, kosiru alaaye bayi, kodesi awon eyan tonfe mo nipa iru eto bayi. Awon alakowe giga gan o mo nkan ton'be lehin aye yi. Wan o ni gbagbo pe aye imi wa lehin aye yi. gege na awujo awon afoju wanyi wa. Awon na sin gbiyanju lati ko wan nikan ti ipinnu aye yi je, nipaataki ara eda eniyan, pe iyato to poo wa laarin iye aye yi ati awon koseemani ara wa bi: jijeun, sisun, asepo oko ati abo, ati igbeja ara. Ninu Bhagavad-gita wan sowipe, manuṣyāṇāṁ sahasreṣu kaścid yatati siddhaye: (BG 7.3) "Ninu opolopo awon eyan, ikan ninu wan le gbiyanju lati ni ilosiwaju ninu aye re." Siddhaye, siddhi. Siddhi niyen, basele ni idari lori ibimo, iku, ojo arugbo ati aisan. ati manuṣyāṇāṁ sahasreṣu kaścid yatati siddhaye. Awon eyan ni aye isin tawa yi, wan o fi be l'ogbon, kosi bonsel mo nkan ti siddhi je. wan rowipe "tin ba ni owo die pelu ile kekere kan ati oko, siddhi niyen je." siddhi ko niyen. lasiko die eyan le kole to da, kosi ni oko ati ebi to dara. sugbon gbogbo eto yi le paare niseju kan, lehin na egbudo tun ara imi gba. Nkan ti awon eyan o mo leleyi, wan o si femo. Oro wan ti paana, kode s'ogbon kankan nibe mo, pelu gbogbo ilosiwaju toni ninu eto eko, ati ilosiwaju awujo wan. Sugbon awa ti soro soke, Krsna ti soro soke.

na māṁ duṣkṛtino mūḍhāḥ
prapadyante narādhamāḥ
māyayāpahṛta-jñānā
āsuraṁ bhāvam āśritāḥ
(BG 7.15)

Awon asiwere wanyo, ton kereju ninu awujo awon eyan, elese ni gbogbo wan je, iru awon bayi kosi bonsele gba imoye Krsna yi s'okan. "Rara. Opolopo ninu wan loni MA, Phd." Krsna sowipe, māyayāpahṛta-jñānāḥ. Sugbon o dabiwipe wan logbon gan , sugbon maya ti yo ogbon ori wan kuro." Āsuraṁ bhāvam āśritāḥ. Awujo awon alainigbagbo yi lewu gan. Nitori eleyi ni awon eyan sen jiya, sugbon wan o fe mu oro yi ni pataki. Nitorina ni Krsna se pe wan ni mūḍhāḥ, asiwere. Na māṁ duṣkṛtino mūḍhāḥ. awa sin gbiyanju lati yi awujo mudha yi pada si aye mimo. Ise tawan gbiyanju agti se niyen. Sugbon wanti salaaye tele, manuṣyāṇāṁ sahasreṣu: (BG 7.3) " Ninu aimoye eyan, iwonba die lole se." Manuṣyāṇāṁ sahasreṣu kaścid yatati siddhaye. Sugbon eleyi o sowipe agbudo daduro. gege bigba tawa ni ile-iwe, Sir Asutosh Mukherjee bere ile-iwe eko giga awon akeko meji tab'eyokan pere lowan be, sugbon owo tan na lori wan si po gan, wan o si ronu pe akeko meji pere lowa ni ile-iwe na. gege na egbe imoye Krsna yi gbudo losiwaju. Kosi wahala ti ko ba ye awon eyan ti o logbon, tabi tonba ko lati wa. Awa gbudo tesiwaju. Ese pupo