YO/Prabhupada 0170 - Agbudo tele awon Gosvamis



Lecture on SB 1.7.8 -- Vrndavana, September 7, 1976

Itumo Saṁhitā ni awon Iwe mimo Veda. Awon asiwere kan wa ton sowipe " Vyāsadeva ko lo ko Bhāgavata, pe Bopadeva kan lo ko." Nkan ton so niyen. Māyāvādīs, aon Nirīśvaravādī. Boya Nirīśvaravādī tabi Māyāvādī, oga wan Śaṅkarācārya, ti se asọye lori Bhagavad-gītā, sugbon kole fowokan Śrīmad-Bhāgavatam, nitoripe ninu Śrīmad-Bhāgavatam wanti to awon nkan jo dada, kṛtvānukramya, Awon Māyāvādī o le fihan pe Olorun o ni irisi. Kosi bon sele se. Nisin wan se nkan to wun wan, wan ka Bhāgavatam bonse fe, sugbon awon eyan to l'ogbon o le f'okan si. Nigbami moti ri awon Māyāvādī pataki tonfe salaaye awon ese-iwe ninu Śrīmad-Bhāgavatam, O sowipe " nitoripe Olorun leyin je, nitorina ti'un yin ba dun, Inu Olorun na tidun." Imoye wan niyen. " Kosi'di pe efe mu inu Olorun dun. Gege na ti oti mimu ba mu inu yin dun, iyen na wipe Inu Olorun dunsi." Bonse salaaye niyen.

Nitorina Caitanya Mahāprabhu ti da asoye wan lebi Māyāvādī Caitanya Mahāprabhu ti sowipe māyāvādi-bhāṣya śunile haya sarva-nāśa (CC Madhya 6.169). Māyāvādī kṛṣṇe aparādhī. Oti sowipe. Ema fi adehun kankan si. Awon Māyāvādī wanyi elese lon je si Krsna. Tān ahaṁ dviṣataḥ krūrān (BG 16.19), Kṛṣṇa na ti sobe. Itara toni fun Krsna si po gan. dvi-bhuja-muralīdhara ni Kṛṣṇa je, śyāmasundara, awon Māyāvādī sowipe Kṛṣṇa o lese, ko lowo. Pe oro irori ni gbogbo eleyi je." Kosi bosele yewan p'ese ton se po gan , sugbon lati kiloo fun awon eyan bi tawa, Caitanya Mahāprabhu ti sowipe " ema lo ba awon Māyāvādī." Māyāvādi-bhāṣya śunile haya sarva-nāśa. Māyāvādī haya kṛṣṇe aparādhī. Oro Śrī Caitanya Mahāprabhu leleyi.

Egbudo ṣọra gan. Ema lo ba awon Māyāvādī. Aimoye awon Māyāvādī ton woso Vaiṣṇava. Śrī Bhaktivinoda Ṭhākura ti salaaye nipa awon eyan bayi pe, ei 'ta eka kali-celā nāke tilaka gale mālā, pe " elesin Kali leleyi. Oni tilaka lori imu re ati ileke lorun, sugbon kali-celā loje." Toba je Māyāvādī, sahaja-bhajana kache mama saṅge laya pare bala. Awon nkan yi wa. Eti wa si ilu Vrndavana. E sora gan. Māyāvādi-bhāṣya śunile (CC Madhya 6.169). Awon Māyāvādī po gan nibi, wan po gan pelu tilaka-mālā, sugbon eyin o le mo nkan to wa l'okan wan. Sugbon awon ācārya lee mo.

śruti-smṛti-purāṇādi
pañcarātra-vidhiṁ vinā
aikāntikī harer bhaktir
utpātāyaiva kalpate
(Brs. 1.2.101)

idamu nikan ni awon eyan yi ma daale. Nitorina agbudo tele awon Gosvami, iwe awon Gosvami, ni pataki Bhakti-rasāmṛta-sindhu, t'awa ti se isotunmo si " adùn ninu ise ifarafun Olouwa, oyeki gbogbo yin ka iwe yi, kebale ni ilosiwaju. Ema bosi owo awon Mayavadi wanyi, ton pera wan ni Vaisnava. Nkan to lewu gan ni.

Nitorina lonse sowipe, sa saṁhitāṁ bhāgavatīṁ kṛtvānukramya cātma-jam. Oro asiri loje Osi ko Śukadeva Gosvāmī ni eto yi.