YO/Prabhupada 0177 - Otito tayeraye ni imoye Krishna yi



Lecture on SB 1.15.28 -- Los Angeles, December 6, 1973

Awa tini ibasepo tinmotinmo yi. gege na taba de ipo yi ta minipa ibasepo tani pelu Olorun tabi Krsna, svarupa-siddhi niyen je. Imo nipa ohun pipe nitumo Svarupa-siddhi. Nibi Suta Gosvami sowipe sauhardena gadhena, santa. Ti awon ore meji ton mora wan tipe pade, idunnu to po loma muwa s'okan awon mejeji. Gege na t'omo to sonu ba pade Baba re, inu baba na ma dunsi gege bi t'omode na. T'oko ati iyawo ba pade lehin igba ti won o si pelu ara wan, inu awon mejeji ma dunsi. Nkan adayeba loje. T'Oga ati iranse ba pade na lehin igba toti pe, inu wan ma dunsi. gege na orisirisiibasepo lale ni pelu Krsna, santa, dasya, sakhya, vatsalya, madhurya. lai ni asepo ni itumo santa, lati ni oye ni pa Oluwa. Apa kan siwaju ni Dasya je. Gege biwipe a sowipe " Alagbara ni Olorun je." Santa leleyi, lati monipa agbara Olorun. Sugbon kosi ise kankan. Sugbon teba losiwaju apa kansi, pe " Alagbara ni Olorun. mon sise fun awon awujo to po, awon ore, awon ololufe, ologbo, aja, mode nife wan. Kilode timiole niife fun eni to lagbaraju? dasya niyen. Lati mowipe alagbara l'Olorun je si da gan sugbon teba losiwaju, " Kilode ti miole sise fun alagbara yi?" gege bi awon eyan ton sise lasan gan, gbogbo wan lonfe fi ise kekere fun ise to gaju. Ise nigbogbo wan, sugbon ise fun ijoba gaju awon ton kere yi lo. Asi rowipe nkan to da niyen. Gege na taba fe sise, agbudo sise fun enito l'agbara ju, nkan to ma funwa ni ifokanbale niyen. santa, dasya niyen.

Ise pelu irẹpọ ti iranse ban sise fun oga, lehin igba die toba le ni ibasepo tinmotinmo pelu oga re, irepo ma wa laarin wam. Moti ri pelu oju mi ni Calcutta. Dokita Bose ore re to dara ju, iwakọ re loje. toba ti joko sinu oko, asi bere sini so gbogbo nkan to wa l'okan re fun iwakọ re gege na iwakọ re sidi ore re to dara ju. gbogbo asiri toni o sofun iwakọ re. O le sele bayi. Ti iranse ba ni irepo to da pelu oga re, oga re a si tu awon asiri fun. Asi ba so gbogbo nkan to fe ko se. Irepo leleyi je. Nkan to gaju eleyi lo ni ... ibasepo laarin baba ati omo, iya ati omo. vatsalya niyen, lehin na ife. gege na awa sini ibasepo pelu Krsna, bakanna tabi awo kan. pe awan yin logo, ninu ise, bi ore, tabi bi obi, tabi ninu ife Agbudo ji gbogbo wan soke. Lesekese teba ji ikan ninu wan, inu wa ma dunsi, nitoripe kolopin. Apeere kanna lowa.. taba yo ika owo wa kuro lara, kosi bi inu ika na sele dunsi. Lesekese teba fi pada, inu re ma dunsi. gege na, gbogbo wa lani ibasepo wa pelu Krsna. Nisin awa o si pelu re mo, sugbon lesekese taba pada loba aledi yenatma suprasidati.

Nitorina egbe imoye Krsna yi dara fun gbogbo awon eyan e gbiyanju lati jisoke imoye yin t'alakoko. Oti wa nibe tele, nitya-siddha krsna-bhakti. nkan tayeraye ni imoye Krsna wa je. Bibeko eyin omo-ilu Europu ati America, odun meta si merin seyin, kosi ikan ninu yin to mo nipa Krsna. Kilode tese ni ifarasi fun Krsna?: Kilode tesi feran re? Afi teyin ba feran re gan, kosi besele fun gbogbo asiko yin fun ise iwaasu yi ni ile-olorun. Eti ni ife fun Krsna. Bibeko koseni kankan nibi tio l'ogbon to kon lo asikore ni ilokulo. Rara. Bawo lose je pe oṣee ṣe? Eyan le sowipe omo-ilu India ni Krsna, tabi Hindu ni Krsna. Taba jebe, kilode ti awon elesin Kristiani se feran re? Se Hindu ni wan na? Rara. Krsna o kin se Hindu tabi Musulman tabi Kristiani. Krsna ni Krsna je. Nkankanna le je pelu Krsna. Irori pe - " Hindu nimi, " Musulman nimi," "Kristiani nimi", " Omo-ilu America nimi," " Omo ilu India nimi" - Nkan yiyan leleyi. Ni oto oro emi nimoje, aham brahmasmi. Brahman to gaju ni Krsna je, param brahma param dhama pavitram paramam bhavan (BG 10.12).

Ani ibasepo pelu Krsna to wa tinmotinmo. Otito oro titilailai leleyi je. Sugbon agbudo jisoke. Sravanadi-suddha-citte karaye udaya. Agbudo daale. gege bi okurin se feran obirin ati obirin se feran okurin. Nkan adayeba niyen. Sugbon tonba pade, ajisoke. Kon se nkan tuntun to sese bere. Sugbon tonba pade, ife yi a jisoke. Ife yi ma jisoke. Ibasepo tani pelu Krsna, nkan adayeba loje. Kon sen ta da sile. Itumo Nitya-siddha niwipe otito oro tayeraye loje. O kon ni nkan ton bo. wanti bo mole. Agbudo yo idaabo yi kuro. lesekese lama pada si ibasepo wa pelu Krsna, Imoye Krsna to daju leleyi je.