YO/Prabhupada 0375 - The Purport to Bhajahu Re Mana part two



Purport to Bhajahu Re Mana -- San Francisco, March 16, 1967

Alebu to po gan wa ninu aye yi. Nitorina agbudo mu ile aye yi ni pataki ka bere sini sise lesekese ninu imoye Krsna. Ibeere toye ki gbogbo wa beere lowo okan wa niyen, " Ore mi, ma fami sinu alebu wanyi. Daakun jekin wa ninu imoye Krsna." Givinda dasa ti salaaye basele ni imoye nipa Krsna. O sowipe,

śravaṇa, kīrtana, smaraṇa, vandana,
pāda-sevana, dāsya re,
pūjana, sakhī-jana, ātma-nivedana
govinda-dāsa-abhilāṣa re

Ireti nitumo Abhilāṣa. On reti lati d'elesin l'ona mesan toyato. sravana ni t'alakoko. Igboran nitumo Sravana. Eyan gbudo gbo lodo awon olori. ibeere ile aye mimo niyen tabi imoye Krsna. Gege bi Arjuna. Lati igboran lose ni imoye re nipa Krsna. Gege na, eyan gbudo gbo lati Krsna tabi awon asoju Krsna. Awon eyan ton salaaye nipa Krsna gege boseje - lati iru eyan bayi loyeka gbo nitoripe lasiko tawayi awa o le gbo lati Krsna fun ara wa. Ilana lati gbo lenu Krsna fun ara re si wa. Krsna wa l'okan gbogbo eyan, a sile gbo latinu re, nibikibi ati nigbogbo igba, sugbon agbudo kekoo lati gbo. Fun nkan bayi agbudo gba iranlowo lowo awon asoju Krsna. Nitorina Caitanya Mahāprabhu sowipe eyan leni ifarasi ise fun Krsna, pelu oreofe Krsna ati oluko wa ninu eto mimo. Guru-kṛṣṇa-kṛpāya pāya bhakti-latā-bīja (CC Madhya 19.151). pelu ore-ofe oluko wa ninu eto mimo, guru, ati ore-ofe Krsna, eyan leri ni anfaani lati sise fun Krsna. gege na ninu Caitanya-caritamrta wan ti salaaye wipe, Asoju Krsna to daju ni oluko mimo yi je. Krsna ma wa si awon elesin re bi Oluko mimo, gege bi orun sen wonu yara bi ina-orun. sugbon orun fun ara re o kin wonu yara yin o si jina gan siwa- sugbon kosibi tikole wo, ina orun. gege na, Krsna a si wonu ibikibi pelu awon agbara re ototo. sugbon lati gba ina yi lati Krsna eyan gbudo gbo. Igboran se pataki gan. Nitorina Govinda dasa ti salaye, śravaṇa. Igboran nitumo Śravaṇa. eni toti gbo awon nkan wanyi dada, ipo keji ni kirtanam. gege bi awon omo-okurin wa, ton ti gbo die dada, nisin wan feran lati korin, wansi lon lati adugbo kan sikeji. boseye koje niyen, kon sepe teba gbo tan, ke dake. rara. ona to kan ni kirtanam. boya eyin korin, tabi eyin kowe, tabi eyin sor, tabi eyin sewaasu, kirtana gbudo wa. gege na śravaṇaṁ kīrtanam, ni alakoko igboran ati orin kiko. orin kiko ati igboran nipa tani? Nipa Visnu, konse fun nkan iranu. Śravaṇaṁ kīrtanaṁ viṣṇoḥ (SB 7.5.23). Wanti salaaye nipa awon nkan wanyi ninu sastra. Awon eyan lasan, wansi gboran, wansi korin na Wan gbo lati iwe iroyin nipa awon oniselu, wansi soro nipa re na "Oh, wan ti dipo fun okurin bayi bayi, wan ti dipo fun okurin bayi bayi, " Igboran ati orin kiko yi wa nibikibi. sugbon teba fe ni igbala, egbudo gbo kesi korin nipa Visnu, koselomi. Śravaṇaṁ kīrtanaṁ viṣṇoḥ. Akewi yi ti korin, Śravaṇa, kīrtana, smaraṇa, vandana, pāda-sevana, dāsya re. Ona orisiri: igboran, orin kiko, iranti, adura ninu ile-Olorun, ise sise fun Olorun. gege na o si fe se gbogbo awon ona mesan wanyi. Ni ona to gaju, pūjana sakhī-jana. Itumo Sakhī-jana ni awon elesein pataki t'Olorun, lati tewan lorun. ati ātma-nivedana. Ara wa nitumo Ātmā, teriba nitumo nivedana. Govinda-dāsa-abhilāṣa. Govinda dāsa ni oruko akewi na, osin salaaye pe lati se awon nkan wany ni nkan soso tofe. o fe igbese aye re ninu ara eda eyan dada. Oro idi orin yi leleyi.