YO/Prabhupada 0377 - The Purport to Bhajahu Re Mana



Purport to Bhajahu Re Mana -- Los Angeles, May 27, 1972

Govinda dasa lo korin yi. Govinda-dāsa-abhilāsa re. Kini ife okan re? Ife okan wa nitumo Abhilāsa. Bhajahū re mana śrī-nanda-nandana: " Ore mi tayataya..." Nitoripe okan wa je ore at'ota siwa. Teba fun okan yin leeko, okan yin ma d'ore si E. sugbon teyin o baa le fun okan yin leeko, lehin a di ota yin to gaju. Sa vai manaḥ kṛṣṇa-padāravindayoḥ (SB 9.4.18). Nitorina okan re gbudo wa ninu ise Krsna nigbogbo iga, lehin na lesekese loma le ni idari lori okan re, asi d'ore re. Gege na Govinda dasa sin soro nipa ife okan re: " Okan mi, ogbudo sise fun Nanda-nandana." Ko sowipe Krsna. O p'oruko Nanda-nandana. Bhajahū re mana śrī-nanda-nandana. T'awa ba pe Krsna l'oruko, inu re o kin dun. sugbon t'awa ba so Krsna: Nanda-nandana, Yaśodā-nandana, Devakī-nandana, Pārtha-sārathi - ninu asepo toni pelu awon elesin re - inu re asi dunsi. Gege na bhajahū re mana śrī-nanda-nandana. Kilode t'awa n'pe ni Śrī-Nanda-nandana? Nisin, abhaya-caraṇāravinda re. Teyin ba ni idaabo ese Krsna, Nanda-nandana, lehin na eyin o le ni idamu kankan, iberu.

samāṣritā ye pada-pallava-plavaṁ
mahat-padaṁ puṇya-yaśo murāreḥ
bhavāmbudhir vatsa-padaṁ paraṁ padaṁ
padaṁ padaṁ yad vipadāṁ na teṣām
(SB 10.14.58)

Bhagavat-darśana leleyi. Padaṁ padaṁ yad vipadām. Ile aye yi, padaṁ padam itumo re niwipe pelu gbogbo igbese tawa gbe, alebu wa pelu e. gege na eyan gbudo ni idaabo Krsna, mahat-padaṁ puṇya-yaśo murāreḥ samāṣritā, Kosi alebu kankan pelu re mo. Abhaya-caraṇāravinda re. Bawo lasele ni idaabo pipe lati Krsna, tio ni jekuru bawa, tawa o leni idamu mo, vaikuṇṭha? Durlabha manava-janama sat-saṅge. Eleyi sese teyin ba ni asepo pelu awon elesin. teyin ba rowipe nisin moti ni ilosiwaju to po gan Mole da gbe, kin si korin Hare Krsna, teyin farawe Haridasa Thakura," Iranu niyen. Kosi besele farawe Haridasa Thakura. Egbudo farawe awon elesin. Durlabha manava-janam sat sange. Sat-sange. Satāṁ prasaṅgān mama vīrya-saṁvido (SB 3.25.25). teyin ba wa pelu awon elesin, teni asepo pelu wan, te ba wan soro, bayi lema ni oye nipa imoye nipa Olorun. Nkan to daju gan lati mo leleyi. Gege bi ile aye yi, awon awujo to wa po gan, Awon onisowo wan ni awujo onisowo, awon ton sewo. Wan ni awujo wan. Ton ba lo sibe, ise wan asi ni ilosiwaju. Gege na, awon ile-idaraya to wa na si po gan. Teyin ba fe moti ke gbadun ara yin, teba losi awon ile-idaraya tesi ni asepo pelu awon eyan yi, gege na eyin na ma ko lati moti, eyin na ma farawe wan. Gege na nkan pataki loje teban k'egbe. Nitorina, egbe imoye Krsna wa, sin fun awon eyan l'aye lati nnbi asepo pelu wa, kon bale ni oye nipa Krsna, nka ti imoye Krsna je. Nitorina Govinda dasa ti fun wa ni ilana, durlabha mānava-janama-sat-saṅge. Mānava. durlabha ni ile aye yi je, o le gan lati ni. Awa o gbudo ni asepo pelu awon aja, awon eye kuroo, sugbon pelu awon siwani. Awon egbe adayeba leleyi. "Awon eye pelu iye kanna lo jon fo papo." Awon eye kuroo, wan fo pelu awon kuroo na, awon siwani ma fo pelu awon siwani. Awon siwani funfun ninu omi to mo, nkan ton feran niyen. Awon kuroo osi feran awon nkan bayi. Awon kuroo si feran ibi ti idoti wa. Nkan to ma mu inu wan dun niyen. gege na, pelu awon amuye toyato, beena ni awon awujo se wa sugbon wan ti funwa nimoran pe durlabha mānava sat-saṅge: ema k'egbe pelu awon eyab ton dabi eye kuroo sugbon pelu awon ton dabi siwani. Teyin ba fun eye siwani ni wara ati omi, oma mu wara na, asi fi omi na sile. gege na eye siwani, haṁsa, paramahaṁsa, itumo re niwipe ninu ara eda eyan yi, eyan to ba mu apa mimo ninu aye yi, tosi fi apa iranu sile, oun lon pe ni hamsa, paramahamsa. Adalu l'ara wa yi je. Nkan aye ni ara wa je, sugbon emi nimi. gege na agbudo mo awon ilana-ise lati fi jade kuro ninu idimu ile-aye yi. A jade kuro ninu ara yi, toba de ti jade asi fi ipaari si ara wa. Apeere toda leleyi. Ina wa ninu igi, gbogbo wa la mo. teba si tan na, teba si je ko gbe, ina ma tan kiakia. ti'ina ban jo, igi na ma gbina. Koni si igi mo. gege na, teyin ba jeki imoye Krsna yi jade, to ban lo dada, igbese ile aye yin ma tan. Ilana to wa niyen. Durlabha mānava-janama sat-saṅge taraha e bhava-sindhu re. bayi, ele lo sodi keji odo ile aye yi. Lehin na eyan le sowipe " tin ba ni asepo pelu egbe imoye Krsna yi, bawo ni mase toju awon ebi mi? Taloma toju iyawo mi ati awon omo mi, awujo mi, awon oremi, awon ife mi? Mosi ni ise to po lati toju." Nitorina lose sowipe, śīta ātapa bāta bariṣaṇa ei dina jāminī jāgi re: " Okan mi, osin sise tole gan bayi." Śīta ātapa. " ninu otutu buruku yi osin sise. Ninu oru osin sise. Ninu omi ojo, eyin o le fi'paari si ise yi." Śīta ātapa bāta bariṣaṇa. " Ise ale, ton sise lale." Awon eyan sis bayi. Śīta ātapa bāta bariṣaṇa ei dina jāminī jāgi re. Tinba sise ni oju ojo wan son wo funmi, tinba si sise lale ,wansi son wo na funmi. Gege bayi awan sise. Kilode ta sen sise? Kilode tasen sise?

śīta ātapa bāta bariṣaṇa
ei dina jāminī jāgi 're
viphale sevinu kṛpaṇa durajana
capala sukha-laba lāgi' re

"gege bayi moti lo asiko mi ni'lokulo, " biphale sevinu, " lati sise fun awon kṛpana durajana, awon awujo, ore ati ife. Kṛpana, awon eyan tio ni sise ninu imoye Krsna, sugbon mosin sise fun wan." Nkan ton sele fun opolopo awon eyan leleyi. biphale sevinu, " Bayi ni mosen lo asiko mi nilokulo Kini igbadun tin mo ri ninu e?" Capala sukha-labha lāgi' re. " imoa ako ati abo fun iseju die, otan." Fun igbadun kekere yi, masi sise to le gan. Nitorina Govinda dasa to sowipe " Eyin fe gbadun ola yi," ei-dhana, yauvana, putra, parijana. Lati ni owo nitumo igbadun ile aye yi, dhana; lehin na jana, awon ton gbekel wa - iyawo, omode, ore, awujo, ati nkan orisirisi to po, ilu wa. Gege na putra, parijana, ithe ki āche paratīti re. " Eyin o le ni igbadan kankan to daju ninu gbogbo eleyi." Kamala-dala-jala, jīvana ṭalamala. Ile aye yi n'gbon. Eyin o le sowipe ile-aye yi ma tan. wanti fun wa l'apeer, kamala-jala-dala. gege bi ewe ododo. teyin ba fi omi sori ewe, kole duro, ama gbon. l'eyikeyi asiko o le gbon danu. Gege na bayi ni ile aye wa seri, o gon. l'eyikeyi asiko - o le tan. Kamala-jala-dala, jivana... bhajahu hari-pada nīti re. Nitorina oye ke sise gan ninu imoye Krsna. Oye ke paari kiku tode. Ise apinfunni yin niyen. Kini imoye Krsna yi? Śravana, kīrtana, smarana, vandana, pāda-sevana... pūjana, sakhī-jana, ātma-nivedana, awon ona mesan ninu ise ifarafun Olorun, govinda-dāsa-abhilāṣa re. Gege na gbogbo wa gbudo ni ife bi Govinda dasa. Śravana kīrtana, awon ise ifarasi Olorun leleyi. Igboran, orin kiko, iranti, arcana, adura si Olorun, vandana, adura gbigba. Awon ona mean na leleyi. Nkan ti ile aye yi wa fun niyen, ati... Pelu ona yi, lawan tan na imoye Krsna yi, tabi imoye mimo. Gege bi'igi ase gbina teba tanna si, gbogbo idaabo wa... Aimokan ti bo emi wa. gege na agbudo jo aimokan yi, lehin na ema ni igbala, ema pada si ijoba Olorun. ipinnu orin yi leleyi.