YO/Prabhupada 0387 - The Purport to Gaurangera Duti Pada
Purport to Gaurangera Duti Pada -- Los Angeles, January 6, 1969
Gaurāṅgera saṅge-gaṇe, nitya-siddha boli māne. Enikeni toba ni oye nipa awon alabasepo t'Oluwa Caitanya, awon eda lasan ko ni won... Awon eda ton ti ni igbala. Nitya-siddha bole māni. Awon olufokansi meta lon wa. sādhana-siddha ni oruko ikan. Itumo Sadhana-siddha niwipe taba tele awon ofin ninu ise ifarafun Olorun, teyan ba si di pipe, wan pe ni sadhana-siddha. Olufokansi imi lon pe ni Krpa-siddha. Kṛpā-siddha, itumo re niwipe teyan o ba le tele awon ofin, pelu ore-ofe awon acarya tabi olufokansi, tabi Krsna, o le de ipo to gaju. Olufokansi imi wa ton pe ni nitya-siddha. Itumo Nitya-siddha niwipe kosi idoti kankan l'aye re. Awon sadhana-siddha ati krpa-siddha ti ko idoti ile aye yi, sugbon ton ba tele awon ofin wanyi, tabi pelu ore-ofe awon olufokansi ati acarya, wan le gonke losi ipo to gaju. sugbon awon nitya-siddha wanyi o ni idoti kankan Wanti ni igbala t'ayeraye. beena awon alabasepo ti Oluwa Caitanya, bi Advaita Prabhu, Srivasa, Gadadhara, Nityananda, Visnu-tattva ni won. Wanti ni igbala tipe. Awon nikan ko, awon Gosvami na... Won si po bayi. Beena wan ti ni igbala tayeraye. Beena o le yewa pe awon alabasepo ti Oluwa Caitanya tini igbala t'ayeraye... Nitya-siddha bale māni, sei yaya vrajendra suta-pāśa. lesekese loma ye ni yiyan lati wonu odo metalokan ti Krsna.
lehin na o sowipe, gauḍa-maṇḍala-bhūmi, yebā jāni cintāmaṇi. gaura-maṇḍala ni ibi ti Oluwa Caitanya ti lo awon asiko idaraya ni ilu iwo oorun Bengal. Ni Navadvipa, ni asiko ojo ibimo re, awon olufokansi man lo si be, wansi lo yipo awon ibi orisirisi ti Caitanya ti lo akoko idaraya. Ojo mesan lon lo. Apa Bangal yi niwon pa ni gaura-maṇḍala. Beena Narottama dasa Thakura sowipe, " Enikeni toba mowipe kosi iyato, laarin ilu yi pelu Vrndavana," tāra haya vraja-bhūmi vāsa, " Nkankana loje pelu eyan ton gbe ni Vrndavana." Lehin na o sowipe, gaura-prema rasārṇarve. Awon ise Oluwa Caitanya dabi okun to kun fun ife Krsna. Nitorina enikeni toba wonu omi okun yi, gaura-prema-rasārṇave, sei taraṅga yebā ḍube. Gege bi awa sen f'omi we, tan sere pelu omi ninu okun tabi odo. Beena, enikeni toba feran lati wonu omi okun ife fun Olorun ti Oluwa Caitanya ti pin lori gbogbo agbaye, eyan bayi ma di olufokansi taya taya t'Oluwa Krsna. Sei rādhā-mādhava-antaraṅga. Eyan tio kin se olufokansi lasan nitumo Antaranga. Awon elesin tayataya niwon. Narottama dāsa Ṭhākura says, gṛhe vā vanete thāke. "Iru awon olufokansi bayi ton ni idunnu ninu egbe Oluwa Caitanya," nitoripe wanti di olufokansi tayataya t'Oluwa...
Nitorina Narottama dasa Thakura sowipe, " Fun awon olufokansi bayi kosejo kankan, toba je aalufa tabi olori ile." Gṛha. Olori ile nitumo Gṛha. Beena konse dandan pe eyan gbodo je aalufa, sannyasi ninu egbe Caitanya Mahāprabhu. gege bi awon Māyāvādī sannyāsī, awon ton rowipe Olorun o kin seyan, Śaṅkarācārya, ni alakoko wan sowipe " E di alufaa, kefi gbogbo nkan aye yi sile keto bere sini soro nipa ilosiwaju ninu eto miko." ninu Sankara sampradaya eyan o le di ikan ninu won afi toba di alufaa, tofi awon nkan aye yi sile. Sugbon nibi, ninu egbe Caitanya, kosi'ru ofin bayi. AdvaitaPrabhu, Olori ile loje. Nityananda, Olori ile na loje. Gadādhara, olori ile na loje. Śrīvāsa, olori iloe na loje. Caitanya Mahaprabhu se igbe yawo lee meji. Beena kon se nkan pataki. Narottama dāsa Ṭhākura sowipe boya eyan di alufaa, tabi o d'olori ile, kon se nkan pataki. To ban sise ninu egbe sankirtana Caitanya, toba si ni oye nipa re na, teyan na ba ni asepo ninu omi okun ise fun Olorun yi, iru eyan bayi tini ominiran. Narottama dāsa Ṭhākura fe ni asepo pelu iru awon eyan bayi. Koko oro niju orin yi leleyi.