YO/Prabhupada 0388 - The Purport to Hare Krsna Mantra



Purport to Hare Krsna Mantra -- as explained on the cover of the record album

Ohun mimo yi - ta wa ban korin Hare Kṛṣṇa, Hare Kṛṣṇa, Kṛṣṇa Kṛṣṇa, Hare Hare, Hare Rāma, Hare Rāma, Rāma Rāma, Hare Hare - ona mimo tale gba lati ji imoye Krsna wa. gbogbo wa lani imoye Krsna, nitoripe eda mimo nigbogbo wa sugbon nitori asepo tani pelu nkan aye yi, lati aimoye igba, imoye wa ti doti pelu awon nkan aye yi. ninu ile aye yi, gbogbo wa lafe gbadun awon nkan aye yi, sugbon beena lasen wonu idimu ile aye yi na. Aimokan yi lon pe ni maya, tabi ijakadi lati ni idari lori awon ofin ile aye yi to lee. Agbudo fi ipaari si Ijakadi yi pelu imoye Krsna tawa ni. Nkan eke ko ni imoye Krsna yi je. Agbara t'alakoko awon eda aye yi ni imoye yi je. Ta ba gbo ohun mimo yi, imoye wa ma jisoke. awon olori dee ti funwa fun asiko tawayi. Pelu irisi ara wa, awa na le riwipe kiko orin maha-mantra yi, tabi Orin alagbara yi tole funwa ni'gbala, lesekese lale jerisi idunnu yi ton wa lati ipo mimo. teyan ba wa lori ipo imoye mimo yi, to oja ipo iye-ara, okan ati ogbon, eyan bayi wa lori ipo mimo. Kiko Orin Hare Kṛṣṇa, Hare Kṛṣṇa, Kṛṣṇa Kṛṣṇa, Hare Hare, Hare Rāma, Hare Rāma, Rāma Rāma, Hare Hare, lat'oke odo metalokan loti wa, O si gaju gbogbo awon imoye aye yi lo - ti'ye-ara, t'okan, ati t'ogbon. Kosidi pe afe mo itumo oro towa ninu mantra na, tabi afe fori ro oro na, tabi iru ogbon toye ka ni tabafe korin maha-mantra yi. lati ipo mimo loti wa, beena, ẹnikẹni le ni asepo ninu orin kiko yi, laini amuye kankan ti tele. Awa ti jerisi. Awon omode tabi aja na le, korin yi. Agbudo gbo roin yi latenu awon olufokansi tonti yasi mimo, bayi a leri ibajade ibee leekana. Agbudo gbiyanju gan, lati ma gbo orin yi latenu awo eyan tio kin se Olufokansi, gege bi wura toba kan enu ejo sen di majele. Oruko Hara lafin pe agbara Olorun. Krsna ati Rama je oruko meji talefi p'Olorun, itumo re ni "igbadun t'ayeraye." Agbara igbadun Olorun ni Hara je. taba pe agabra Hare yi, a ranwa lowo lati ba Olorun. Agbara ile-aye yi ton pe ni mayā, ikan ninu awon agbara Olorun to po, awa na si je agbara iwonba die t'Olorun. Agbara to gaju awonn ohun elo aye yi ni awon eda. ti agbara giga yi ba ni asepo pelu agbara kekere yi, nkan tio da loje. sugbon ti agbara mimo iwonba die yi ba ni asepo pelu agbara mimo, Hara, inu re madun, nkan adayeba fun awon eda loje. Awon oruko meta wanyi, Harā, Kṛṣṇa ati Rāma, awon eso orin mahā-mantra leleyi, orin kiko yi ni ona talefi p'Olorun ati agbara re, Hāra, lati fun awon eda ni idaabo. Orin kiko yi dabi ekun omode fun iya re. Iya Hara lole fun wa ni iralowo lati gba ore-ofe baba wa, Hari, tabi Krsna, Olorun a si farahan si awon olofokasin ton daju bayi. Kosona imi ni asiko tawayi to daju to, lori eto mimo, bi kiko orin mahā-mantra, Hare Kṛṣṇa Hare Kṛṣṇa, Kṛṣṇa Kṛṣṇa Hare Hare, Hare Rāma Hare Rāma, Rāma Rāma Hare Hare.