YO/Prabhupada 0394 - The Purport to Nitai-Pada-Kamala
Purport to Nitai-Pada-Kamala -- Los Angeles, January 31, 1969
Nitāi-pada-kamala, koṭi-candra-suśītala, je chāyāy jagata jurāy. Orin Narottama dāsa Ṭhākura, ācārya pataki ninu Gauḍīya-vaiṣṇava-sampradāya. Oti ko awon orin to po nipa imoye Vaisanava, won dee ti jerisi pe awon orin na wa pelu ilana awon ofin Veda. Beena nibi Narottama dasa Thakura sin korin pe " Gbogbo agbaye yi n'jiya ninu ina ile aye yi. Nitorina, tetan ba ni idaabo ese bi ododo Oluwa Nityananda.." Ti ojo ibimo re je oni, 31st, l'osu Sere, l'odun 1969. beena agbudo gba awon ilana Narottama dasa Thakura ni pataki pe taba fe ni itura lowo isoro ina ile aye yi, agbudo gba idaabo labe ese bi ododo t'Oluwa Nityananda, nitoripe osi tutu bi ina aimoye osupa, Itumo re niwipe lesekese l'eyan ma ni bugamu t'alafia. Gege bi okurin ton sise lataaro, toba wa sabe ina osupo, asi ni itura. Beena, ti awon okurin ton feran igbadun aye yi ba wa sabe idaabo Oluwa Nityananda lesekse lonma ni itura yi. Lehin na o sowipe,
- nitāi-pada-kamala, koṭi-candra-suśītala,
- je chāyāy jagata jurāy,
- heno nitāi bine bhai, rādhā-kṛṣṇa pāite nāi,
- dharo nitāi-caraṇa du'khani
Teba fe " Pada si ile, si odo metalokan, kesi di alabasepo pelu Radha ati Krsna, nkan to daju ni ke gba idaabo labe Nityananda." Lehin na oswipe, se sambandha nāhi jā'r, bṛthā janma gelo tā'r: " Eyan tio ba le pade Nityananda, lehin na eyan gbudo ronu pe ile aye re ti baje." Bṛthā janma gelo, laisi nkankan nitumo bṛthā, aye nitumo janma. Gelo tā'r, to baje. Nitoripe koiti ni asepo pelu Nityananda. T';ayeraye nitumo Nitya. Idunnu nitumo Ananda. Fun igba die ni idunnu aye yi wa fun. Iyato to wa niyen. Nitorina awon ton l'ogbon, wan o fe ni nkankan se pelu idunnu aye yi. Gbogbo wa, awon eda, lan sa tele igbadun. sugbon igbadun t'an sa tele yi, fun igba die lowa. Konse igbadun gidi, nityānanda ni igbadu gidi to wa, igbadun tayeraye. Beena enikeni tio bani asepo pelu Nityananda, oye ka mo wipe aye re ti baje.
- se sambandha nāhi jā'r, bṛthā janma gelo tā'r,
- sei paśu boro durācār
Narottama dāsa Ṭhākura sin lo awon oro ikanra nibi. O sowipe eranko ni iru eda bayi je, eranko teyan o le ni idari lori re. Gege bi awon eranko kan wa ti awa o le toju si ile, enikeni tio ba ni asepo pelu Nityananda, oyeka wo bi eranko latinu'gbo. Sei paśu boro durācār. Kilode? Nitroripe nitāi nā bolilo mukhe: "koi ti da'ruko Nityananda." majilo saṁsāra-sukhe, " kosi wonu igbadu ile- aye yi." Vidyā-kule ki koribe tār. " Oniranu yi mo wipe, eto eko re ati ebi re, ati awon asa ati orile-ede re kole fun ni iranlowo kankan?" Awon nkan wanyi o le fun ni iranlowo. Fun igba die ni awon nkan wanyi wa fun. Sugbon tawa bafe igbadun tayeraye, agbudo pade Nityananda. Vidyā-kule ki koribe tār. Eto eko nitumo Vidyā, ati kula, itumo re ni ebi, orile-ede. Gege na a le ni ebi to da, tabi ipo gidi lati orile-ede wa, sugbon lehin tab f'ara le, awon nkan wanyi o le ranmi lowo. Ise mi ma tele mi lo, dandan nipe mo gbodo gba ara imi lati ibajade awon ise timo se. O le je nkan imi to yato si ara eda. Gege na awon nkan yi o le fun wa ni idaabo tabi igbadun gidi. Gege na Narottama dasa Thakura ti salaaye pe vidyā-kule ki koribe tār. Lehin na o sowipe, ahaṅkāre matta hoiyā. "Ton sara leyin awon igberaga iranu ati idanimo..." Idanimo eke pelu ara yi ati igberaga nitori awon asepo tani pelu ara yi, nkan ton pe ni ahaṅkāre matta hoiyā. Awon eyan sa tele igberaga eke yi. Ahaṅkāre matta hoiyā, nitāi-pada pāsariyā. Nitori igberaga eke yi, asin rowipe, " Oh, tani Nityananda? Kilo le se funmi? Ko kanmi." Awon aami igberaga eke ni gbogbo eleyi. Ahaṅkāre matta hoiyā, nitāi-pada pāsa... asatyere satya kori māni. Ibajade towa niwipe an reti nkan eke. Fun apeere, moti gba ara yi. Moyato si ara yi. Nitorina, pelu awon idanimo eke wanyi, idinmu ile aye yi lori mi tin po si. Beena eyan tba ni igberaga nitori ipo eke yi, ahaṅkāre matta hoiyā, nitāi-pada pā... asatyere satya kori māni, asi gba nkan tio da fun nkan to da. Lehin na o sowipe, nitāiyer koruṇā habe, braje rādhā-kṛṣṇa pābe. Teyin ba fe gba losi ile, si odo metalokan, edakun e bere ore-ofe Nityananda.
- nitāiyer koruṇā habe, braja rādhā-kṛṣṇa pābe,
- dharo nitāi-caraṇa du'khāni
" E dakun e mu so ese Nityananda to daabi ododo." Lehin na o sowipe, nitāiyer caraṇa satya. E yan le rowipe taba di awon idaabo orisirisi mu, sugbon ni ile aye yi koni pe katori wipe koseyi ninu won to daju, beena, kasowipe a mu ese Nityananda todabi ododo danni - o le je nkan eke na. sugbon Narottama dāsa Ṭhākura ti daniloje pe, nitāiyer caraṇa satya: " nkan eke ko loje. Nitoripe Nityānanda wa tayeraye, ese re na ma wa fun ayeraye." Tāṅhāra sevaka nitya. Enikeni toba si gba ise Nityananda, eni na ma wa titi lailai. Lai wa tayeraye, koseni tole sise fun eni to wa tayeraye. Ilana Veda niyen. Lai di Brahman, koseni tole pade Brahman to gaju. Beena koseni tole wonu ina lai ni ara ina. lai d'omi, kosei tole wonu omi. Beena, lai di mimo, koseni tole wonu odo metalokan. Beena nitāiyer caraṇa satya. Teyin ba mu ese Nityananda, lesekese lema yasi mimo. Gege beyan toba fowo kan ina mọnamọna, lesekese loma mu. Nkan adayeba niyen. Beena, idunnu tayeraye ni Nityananda, teyin ba fowokan Nityananda l'ona kan tabi keji, lesekese lema ni idunnu. Tāṅhāra sevaka nitya. Nitorina eyan to ba ni asepo pelu Nityananda, eni na wa t'ayeraye.
- nitāiyer caraṇa satya, tāṅhāra sevaka nitya,
- dṛḍha kori' dharo nitāir pāy
Beena emu ese re danni dada. Narottama boro duḥkhī, nitāi more koro sukhī. Ni ipaari, Narottama dāsa Ṭhākura, olupilẹṣẹ orin yi, Osi dara si Nityananda, "Oluwa mi, inu mio dun. Gege na edakun e jekinumi dun. Kesi toju mi s'apa kan ese yin to dabi ododo." Koko oro orin yi leleyi.