YO/Prabhupada 0395 - The Purport to Parama Koruna



Purport to Parama Koruna -- Los Angeles, January 16, 1969

Parama koruṇa, pahū dui jana, nitāi gauracandra. Orin ti Locana dāsa Ṭhākura ko leleyi, olufokansin Oluwa Caitanya, bi egbe loje si. O si ko iwe kan, Caitanya-maṅgala, ton salaaye nipa awon ise Oluwa Caitanya. Iwe t'olokiki leleyi, Caitanya-maṅgala. Osi ti ko awon orin to po. opolopo ninu awon Vaisnava, akewi mimo niwon. Ikan ninu awon amuye 26 ti awon Vaisnava niyen. Beena osowipe " Awon Oluwa meji wanyi," nitāi gauracandra, "Oluwa Nityananda ati Oluwa Gauranga, tabi Oluwa Caitanya, awon eda to l'aanu gan lonje." Saba avatāra-sāra śiromaṇi. " Awon ni koko gbogbo awon eda to ku." Wanti salaaye nipa awon eda wanyi ninu Bhagavad-gita, pe ibikibi ti asise ba wa ninu awon ilana esin, ati ibi t'awon eyan tin se iranu, ni asiko yi ni Olorun an wa, tabi ko farahan ninu ile aye yi, lati toju awon olooto ati fi ipaari si awon elese. ise apinfunni t'eda yi leleyi. Gbogbo awon eda wanyi ni nkan meji yi. Oluwa Krsna, o dara gan, alaanu loje, sugbon alebu nla loje si awon esu. O si dabi ãra fun awon esu, awon gopi si ri bi orisa ife (cupid) to lewa ju. beena ninu Bhagavad-gītā wan sowipe, ye yathā māṁ prapadyante (BG 4.11). beyan se teriba si, beena ni Olorun asi f'ara re han fun.

Eda toma kehin ni asiko tawayi, a wa lati pa awon eyan. Sugbon o ma pe koto wa. Sugbon nibi Oluwa Caitanya, Lati pa awon eyan ko ni ise re, lati ranwa lowo nikan. Aami idayato t'Oluwa Caitanya niyen. Nitoripe lasiko tawayi, isekuse ninu esin ti po gan. Sugbon t'Oluwa Caitanya bafe pa won, kosi bonsele ni'gbala. Niotoro enikeni t'Olorun ba fiku pa, eni na ma ni igbala. Sugbon kole losi awon isogbe-orun, won ma wonu ina Brahman bi awon alainigbagbo na. Ni oro imi, ipinnu aye awon alainigbagbo nkankan loje pelu awon ton je ota s'Olorun. Ise tole ko niyen. Beena aanu Oluwa Caitanya po gan nitoripe on fun gbogbo eyan n'ife Krsna. Ijuwe ti Rūpa Gosvāmī fun Oluwa Caitanya niwipe oun l'eda to laanu ju nitoripe on fun gbogbo eyan ni Krsna nibikibi toba lo, laisi eto idayato kankan. Beena Locana dāsa Ṭhākura sowipe parama koruṇa, pahū dui jana, nitāi gauracandra. awon ni koko gbogbo awon iseda wanyi. Kevala ānanda-kanda. Ise iwaasu wan si dara gan. Caitanya Mahāprabhu ti salaaye " E korin Hare Krsna, ke jo dada, tba si ree yin, e sinmi ke je ounje Krsna prasadam." Ilana to fi sile si dara gan. Kevala ānanda-kanda. nigbato wa ni Jagannatha Puri, niroole lojojumo lon korin, ton jo. Lehi igbati ijo yi ba tan, asi pin Jagannatha prasadam. awon eyan to po gan ma koja lojojumo laale. Beena nkan to ma funwa ni idunnu ni egbe yi je. Kevala ānanda-kanda.

Lehin na osi p'ase, bhajo bhajo bhāi, caitanya nitāi. " Aburo mi okurin, gbiyanju lati s'adura si awon olorun mejeji wanyi, Caitanya ati Nityananda," sudṛḍha viśvāsa kori', " pelu igbagbo ati idaniloju." Eyan gbodo nigbagbo ninu awon oro Oluwa Caitanya. Oluwa Caitaya sowipe " E ma korin lo. Teyin ban korin, aye yin ma wa ni pipe." Oto oro leleyi. Afi tawa ban korin, kosi basele daamo, sugbon awon ton korin, wan jerisi, wansi ri gbogbo nkan to dara aye yi gba. Beena agbodo korin mantra yi pelu igbagbo ati idaniloju. sugbon amuye kan soso teyan gbodo ni, o sowipe, viṣaya chāḍiyā, se rase majiyā, mukhe bolo hari hari. Agbudo korin peu igbagbo ati idaniloju sugbo agbodo se jeje, ka ma bere si gbadun ara wa. Viṣaya chāḍiyā, itumo viṣaya ni igbadun ara wa. Lati fisile nitumo chāḍiyā. Agbodo fi ipaari si igbadun iye ara wa. Ninu ile aye yi, o daju pe ani awon iye ara wa, a de tin lo wan ti pe. Kosi basele daa duro. Kosejo pe afe da wan duro, sugbon afe lo wan dada. Gege biwipe a fe jeun. Jijeun nitumo Viṣaya, sisun, imo ako ati abo ati igbejua ara eni. Beena kon sepe awa o gbudo se awon nkan wanyi mo. sugbon agbodo tun won wo lati jekon ranwa lowo ninu imoye Krsna wa. Gege bi jijeun. Awa o gbodo jeun nitorii itowo nikan. Agbudo jeun lati jek'ara wa dada fun ise imoye Krsna. Gege na awao gbodo fi ipaaro si jijeun, sugbon niwonba to da. Beena, imo ako ati abo. Awa o le fi ipaari si imo ako ati abo. Sugbon ofin to wa niwipe teba se igbeyawo ele ni imo ako ati abo yi lati le bimo, awon omo pelu imoye Krsna. Bibeko ema se. gbogbo nkan loye ka se niwonba to ye. Kosejo pe fi ipaari si igbeja ara eni. Arjuna si jagun, nitoripe Krsna si sofun ko se. Beena gbogbo nkan lowa nbe. Kosi nkan tema daduro. Beena agbudo se kobale ranwa lowo ninu imoye Krsna wa. Viṣaya chāḍiyā. Awa o gbodo gba awon viṣaya wanyi, awon nkan merin wanyi ton ba ara waja, jijeun sisun, imo ako ati abo, ati igbeja ar aeni, fun igbadun ara wa. rara. Awon oniselu wan ja fun igbadun iye ara wan. Fun awon eyan ko lon sise. fun ilosiwaju wan ninu eto oniselu, nitorina losen ja. Ewo ni iru ija bayi je. Sugbon toba yeka ja lati gbeja awon eyan, iru ija bayi loye ka se. Agbudo fi eto igbadun yi sile, tabi ilana igbadun ara wa.

Dekho dekho bhāi tri-bhuvane nāi. Lehin na o sowipe, "Se ri, koselomi too laanu bayi." Paśu pākhī jhure, pāṣāṇa vidare. Pelu ore-ofe re awon eye ati eranko gan won toju ara won. Niotoro, Nigbati Caitanya Mahaprabhu gba inu igbo ton pe ni Jhārikhaṇḍa, ni orile ede India, Iranse re lo tele, oun nikan lo wa, nigbaton koja ninu aginju yi, o fowo kan ekun kan. Ekun na sun, nigbato fowo kan o daun pel'ariwo. Eni ton tele Caitanya Mahaprabhu si bere sini ronu, " O tan funwa nisin." Sugbon niotoro Caitanya Mahaprabhu bere lowo ekun na, " Kilode tosen sun? dide soke. Korin Hare Krsna."Ekun na si bere sini jo. Nkan to seleniyen. Nigbati Caitanya Mahaprabhu sewaasu egbe Hare Krsna yi, awon ekun, awon agbọnrin,... Gbogbo eyan lo dasi. A mowipe awa o lagbara bayi. Sugbon o se se,... Ati ri awon aja ton jo ni sankirtana. Nkan to sese.. sugbon awa o le dan iru nka bayi wo. Sugbon Caitanya Mahaprabhu lagbara lati sofun awon ekun kon jo, ale sofun awon eda eniyan kon jo. Egbe to da gan leleyi.

beena paśu pākhī jhure, pāṣāṇa vidare. okuta nitumo Pāṣāṇa Awon eyan ton ni okan tole bi okuta, okan wan ma yo ton ba korin Hare Krsna yi. Nkan tati jerisi leleyi. Pāṣāṇa vidare, śuni' jāra guṇa-gāthā. tawa ba n'gbo awon itan idaraya at'amuye Oluwa Caitanya, awon okurin pelu okan todabi okuta, okan wan ma yo. Orisirisi apeere lowa, Jagāi Mādhāi. Awon eda elese to po, ti wa sori ipo mimo to gaju yi. Lehin na Locana dāsa Ṭhākura sowipe viṣaya majiyā, rohili poriyā. "lailorire, moti wole si idimu awon igbadun ara mi tabi iye ara mi, pe moti gbagbe ese Caitanya Mahaprabhu to dabi ododo." Viṣaya majiyā, rohili poriyā, se pade nahilo āśa. "mio si nife fun ese Oluwa Caitanya toda bi ododo." Beena kilode tose ri bayi? O sukun pe āpana karama, bhuñjāye śamana, pe "mon jiya awonn ese nkan timo ti se leyin, pe mio ni ifarasi egbe imoye Krsna. Ijiya ti Yamaraja fi je mi niyen, alabojuto iku." Niotooro, egbe imoye Krsna yi dara gan, awon eyan lasan gan lee ni ifarasi. sugbon teyan o ba ni ifarasi oye koyewa wipe alabojuto iku lon fiya je. Sugbon tawa ba gbokanle ilana orin kiko yi, Yamaraja gan, alabojuto iku, kosi bosele fiya jewa. Ase Brahma-saṁhitā niyen. Brahma-saṁhitā sowipe, enikeni toba gba ile aye ifarafun Oluwa yi, gbogbo ese toti se lehin ma pari lesekese. gbogbo wa gbudo ni asepo pelu egbe imoye Krsna yi, e korin Hare Kṛṣṇa Hare Kṛṣṇa Kṛṣṇa Kṛṣṇa Hare Hare, Hare Rāma Hare Rāma Rāma Rāma Hare Hare.