YO/Prabhupada 0398 - The Purport to Sri Krsna Caitanya Prabhu



Purport to Sri Krsna Caitanya Prabhu -- Los Angeles, January 11, 1969

Śrī-kṛṣṇa-caitanya prabhu doyā koro more, tomā binā ke doyālu jagata-māyāre. Narottama dāsa Ṭhākura lo ṣajọ orin yi. Adura ton gba niwipe " Oluwa mi, E dakun E s'aanu funmi, nitoripe talole s'aanu funmi ju yin lo nigbogbo agbaye yi?" Ni pipe, otooro leleyi je. Narottama dāsa Ṭhākura nikan ko,sugbon Rūpa Gosvāmī na, O si gbadura si Oluwa Caitanya nigbaton jo pade ni Prayāga, Allahabad, ninu ipade t'alakoko Oluwa Caitanya ati Rūpa Gosvāmī ni Prayāga. Lasiko yi ni, Śrīla Rūpa Gosvāmī sowipe, " Oluwa mi, Eyin l'eda to laanu ju ninu gbogbo eda. Nitoripe eyin pin ife Krsna, imoye Krsna." Ni oro imi, nigbati Krsna wa lori aye yi fun ara re, O kan so funwa pe e teriba, sugbon ko seto pinpin ara re. O sofun wa wipe " ni alakoko E teriba." Sugbon nibi, Oluwa Caitanya, toje Krsna fun ara re, ko funwa ni ipo kankan. O kon pin lofe, " Egba ife Krsna." Nitorina Oluwa Caitanya l'eda to laanu ju, Narottama dāsa Ṭhākura ti sowipe " E dakun e saanu funmi. oninurere leyin je nitoripe E ti ri awon eda elese ile aye yi, E de ti s';aanu fnn won. Sugbon oye ke mo wipe emi l'elese to gaju. Koseni to se jumi lo." Patita-pāvana-hetu tava avatāra. "Lati wa fun awon eda yi nigbala lese wa. Sugbon mofe kemo wipe eyin o le ri eni to wosi le jumi lo. Nitorina emi looye ke fun nigbala lalakoko." Lehin na osi gbadura si Oluwa Nityananda. O sowipe, hā hā prabhu nityānanda, premānanda sukhī. "Oluwa mi Nityananda, nigbogbo igba leyin kun fun ayo, Beena moti wa ba yin nitoripe ibanuje mi po. Beena tryin ba koju simi, inu mi na asi dun." Lehin na osi gbadura si Advaita Prabhu: hā hā prabhu sītā-pati advaita gosāi. Sītā l'oruko iyawo Advaita Prabhu. Nitorina lon sen pe ni sītā-pati nigbami. Beena "Advaita Prabhu mi, oko Sītā, edakun E s'aanu funmi, Nitoripe teyin ba s'aanu funmi, Oluwa Caitanya ati Nityananda na ma s'aanu funmi." Idi fun eyi niwipe, Advaita Prabhu lope Oluwa Caitanya ko sokale wa. Nigbati Advaita Prabhu ri gbogbo awon elese eda, ton kan gbadun ara won lai ni imoye Krsna, o si saanu fun won, sugbon o so wipe, oun l'agbara lati fun won ni gbala fun ara re. Nitorina lose gbadura si Oluwa Krsna pe " E wa fun ara yin. Afi teyin ba wa fun ara yin, kosi basele fun awon eda yi nigbala." Oluwa Caitanya si farahan nitori pipe si. Narottama dāsa Ṭhākura sin gbadura si Advaita Prabhu pe " teyin ba s'aanu funmi, gege na Oluwa Caitanya ati Nityananda na ma s'aanu funmi." Lehi na o gbadura si awon Gosvāmīs. Hā hā svarūpa, sanātana, rūpa, raghunātha. " Gosvāmī Prabhu taya mi," svarūpa. Akọwé ti ara ẹni ni Svarūpa Dāmodara je si Oluwa Caitanya. Nigba gbogbo lowa pelu Caitanya Mahāprabhu, ounkooun toba de fe, lesekese loma seto na. awon iranse meji, Svarūpa Dāmodara ati Govinda, nigba gbogbo lonwa pelu Oluwa Caitanya. Gege na Narottama dāsa Ṭhākura sin gbadura si Svarūpa Dāmodara. Ati awon Gosvāmī. Awon oluko Oluwa Caitanya to tele ni awon Gosvāmī mefa: Śrī Rūpa, Śrī Sanātana, Śrī Bhaṭṭa Raghunātha, Śrī Gopāla Bhaṭṭa Gosvāmī, Jīva Gosvāmī, ati Raghunātha dāsa Gosvāmī. Awon Gosvami mefa wanyi keko lati Oluwa Caitanya fun ara re, latile pin imoye egbe Krsna yi. Narottama dāsa Ṭhākura na sin gbadura fun ore-ofe wan. lehin awon Gosvami mefa, ācārya to tele ni Śrīnivāsa Ācārya. o gbadura si, Śrīnivāsa Ācārya. Niotooro, Narottama dāsa Ṭhākura je ikan ninu awon akeko ninu ile eko Śrīnivāsa Ācārya. Tabi die loku kon j'egbe. Rāmacandra, Rāmacandra Cakravartī l'ore re. On gbadura wipe " Mosi feran lati ni asepo pelu Rāmacandra." Asepo awon olufokansi. ilana to wa niwipe agbudo gbadura fun ore-ofe awon ācārya to gaju. Agbudo ni asepo pelu olufokansi mimo. Asi rorun funwa lati ni ilosiwaju ninu imoye Krsna, lati gba or-ofe Oluwa Caitanya ati Oluwa Krsna. Lakotan orin Narottama dāsa Ṭhākura leleyi.