YO/Prabhupada 0437 - Conchshell Is Considered Very Pure, Transcendental



Lecture on BG 2.8-12 -- Los Angeles, November 27, 1968

Teyan ba fi awon Upanisad wanyi fi jerisi, oro ton so ma daju. Śabda-pramāṇa. Ijerisi nitumo Pramāṇa. Ijerisi.. teba fe ki oro yin daju... Gege boseye ke jerisi ninu ile-ejo, beena ninu asa Veda, pramana ni ijerisi to wa. Ijerisi nitumo Pramana. Śabda-pramāṇa. Ijerisi meta lowa ti awon alakowe ti Veda gba. Ikan je prataksa. Oun tale foju ri nitumo Pratyaksa. Gege bi mosen ri yi, eyin na ri mi. Mo wa nibi, eyin na wa nibi. Nkan tale foju ri leleyi. Imi tunwa ton pe ni anumana. Kasowipe mo sese de, ninu yara yen, mio mo boya eyan wa nibe tabi rara. sugbon o l'ohun ton tibe jade, mole ronu wipe, " Oh, o dabi wipe enikan wan'be." Nkan ton pe ni anumana niyen. Ninu eto ogbon nkan ton pe ni àkùnàyàn. Ijerisi na si wa nibe. Tinba le fun jerisi nkan, pelu ijerisi to daju, osi saa na. Beena nkan tale foju ri lonpe ni àkùnàyàn tabi ijerisi. sugbon ijerisi to daju lo titi ni sabda-pramana. Śabda, śabda-brahman. Veda nitumo re. Teyan ba le mu iferisi re lati awon Veda oye ka gba bee. Koseni to le jiyan pelu awon ijerisi ti Veda. Ilana to wa niyen. Kilode to se ri bayi? Caitanya Mahāprabhu ti salaaye fun wa pel'apeere to daa. O wa ninu Veda. Gege bi awa sen fi "conchshell" niu ile adura. Conchshell yi si je nkan mimo, bibeko bawo lasele fi siwaju ile adura wa, asin fenu fun bi fere? teba fe s'adura pel'omi lati conchshell. bawo lesele se? Sugbon kini conchshell yi? Egungun eranko ti conchshell yi. Egungun eranko loje. Sugbon awon ilana Veda sowipe teba fowokan egungun eranko oye ke lowe lesekese. Eti ko doti niyen. Nisin eyan lesowipe, " Oh, idamu wa ninu oro yi. Nibi kan eso wipe teyan ba fowokan egungun eranko, lehin na o ye kolowe lesekese, nibi etun sowipe egungu wa ninu ile adura. idamu ko leleyi? T'egungun erank ba je ewo, kilode teyin se fi sinu ile adura? T'egungun erank masi je nkan mimo kilode toye ka we taba fowokan?" E ma ri awon idamu bayi ninu Veda. Sugbon nitoripe Veda ti sobe pe egungun eranko doti, agbodo gba bee. sugbon egungun erank yo je mimo. gege bi awon akeko wa man ronu wipe kilode t'awa o kin j'alubosa, sugbon efo l'alubosa je. Beena śabda-pramāṇa itumo re niwipe, agodo gba ounkoun ti awon Veda baso lai jiyan. Itumo wa, kosi idamu kankan. Gege bi moti sofun yin pe igbe maalu. Igbe maalu je mimo, gege bi awon Veda se so. Ni India won lo fise ogun kokoro. Ni awon abupe, igbe maalu po gan won si fi sinu gbogbo ile na lati pa awon kokoro. Niotooro teba fi igbe maalu sinu yara yin, toba gbe tan, em ri wipe, gbogbo yara na mo. Nkan tele jerisi teba se. Dokita kan pel'roku Ghosh, oni sayensi to daju gan ti wo ara maalu dada, lati mo idi toje wipe awon maalu se pataki ninu iwe Veda? Osi riwipe maalu ni gbogbo awon ountole pa kokoro ninu re.