YO/Prabhupada 0444 - Gopis Are Not Conditioned Souls. They Are Liberated Spirits
Lecture on BG 2.8-12 -- Los Angeles, November 27, 1968
Prabhupāda: Hm?
Olofokansi: Moti ka nibikan ninu awon iwe te ko pe lati le mo nipa awon eto asiri laarin Radha ati Krsna, eyan gbodo sise fun awon gopi toje iranse si awon gopi, mosi rowipe eyin je iranse awon gopi. Se bee ko? tabi... bawo ni mosele di oniranse si awon gopi?
Prabhupada: Gopi, eda lasan ko ni awon eyan wanyi. Awon emi to wa ni pipe. Beena e gbodo jade kuro ninu idimu aye yi. Lehin na ele bere sini soro nipa ise si awon gopi. Ema gbiyanju lati sise fun awon gopi nisin. E gbiyanju lati jade nibi na. Asiko ma wa teyin ma sise fun awon gopi. Ninu ipo ile aye yi tewa kosi nkankan talese. Krsna lon se gbogbo e. Sugbon ti funwa laaye lati sise fun ninu arcā-mārga. Gege bi awa sen sise fun awon irisi Krsna, tan fun ni prasada pelu gbogbo awon ofin. Beena agbodo ni ilosowaju ninu eto yi, orin kiko, igboran, ati addura ninu ile ajosin, fifun ni prasadam. bayi lama ni ilosiwaju, lehin na Krsna ma farahan si e, beena ema ni oye nipa ipo yin, boseye ke... Itumo awon Gopi niwipe won sise nigbogbo igba ninu ise Olorun. Beena asepo tayeraye yi ma farahan si yin. Agbodo duro fun asiko yi. lesekese yi aw ao le bere sini huwa bi awon gopi. Nkan to da niwipe iwo fe sise fun awon gopi, sugbon lesekese ko. Asiko na ma wa. Lesekese bayi agbodo teloe awon ofin ati ise wanyi.