YO/Prabhupada 0582 - Krishna is Sitting Within the Heart



Lecture on BG 2.21-22 -- London, August 26, 1973

Beena idanwo yi wa lowo wa. T'awa ba yole ni asiko mangala-arati, itumo re niwipe awa o ni ilosiwaju ninu eto mimo. teyan ba si mura, " Nisin asiko mangala-arati ti ya, eje kin dide, kin se ise yi," Lehin na nkan mimo niyen. Enikeni lese idanwo yi. Bhaktiḥ pareśānubhavo viraktir anyatra syāt (SB 11.2.42). Nkan mimo nitumo Bhakti. Beena lesekese teyan ba fowokan emi mimo to gaju yi, viraktir anyatra syāt, Kosi igbadun ninu ile ayey yi. Beena, Krsna si wa nibe. Krsna si wa lokan wa, emi na wa ninu okan mi, gege bi ore meji to wa ninu ile oti kanna. Wanti salaye ninu Upanisad. Samāne vṛkṣe puruṣo nimagnaḥ. Won joko lori ipo kanna. Nimagnaḥ. Eye na sin je awon eso yi lati igi na, tabi emi jiva, eda eyan, osin sise toma fun ni ijeere re. Kṣetra-jña. Wanti salaye gbogbo eleyi. Kṣetra-jñaṁ cāpi māṁ viddhi sarva-kṣetreṣu bhārata (BG 13.3). Onile ati eni tan ya ile na lo. Emi nimon ya ile na lo, Krsna ni onile. Nitorina, oruko imi fun Krsna ni Hṛṣīkeśa. Hṛṣīkeśa. Beena Oun ni onile owo ati ese ati oju mi, gbogbo nkan, gbogbo awon iye ara mi. Mo kan ya lo. Emi ko nimo ni. Sugbon ati gbagbe. Gege tobajepe eyin wa ninu ile te yalo, eyin le yalo. Eyin ti ni iwe-ase lati gbe ninu yara na. Eni ko leni ile na. Sugobn teyin ba rowipe eyin le ni ile na, nkan tonpe ni, stena eva sa ucyate (BG 3.12), lesekese loma gba ijuwe tio daju.

Beena egba bayi, ara eda yi, orile-ede yi, ilu yi tabi agbaye yi tabi gbogbo agbaye na, kosi nkankan toje tiyin. Krsna loni gbogbo e. sarva-loka-maheśvaram ni oniloe na je (BG 5.29). Krsna sowipe, " Emi ni onile." Asise towa niwipe awa o mo eni to ni, botilejepe awa wa ninu ile na, awa o lo aye wa dada. Ipo aye yi leleyi. Ko da. Bibeko, ijuwe na ti wa nibe, ijuwe na ti wa nibe. Gbogbo'gba lon ranyin lowo. sugbon aisan towa niwipe awa sin rowipe awa lani. asi fe se bose wuwa, ipo aye yi niyen. lati sise fun onile na nise mi, konse temi. Nitorina, ipo aye mi leelyi, Krsna ti da mi, sugbon gbogbo wa lawa pelu Krsna. Sugbon iranse tayeraye laje. gege bi ika owo wa se wa pelu ara wa. Ika owo ko yato si ara wa. Nigbaton bimi, ika owo mi na wa saye. Beena, nigbati Krsna wa nibe, Krsna o ni ibimo. Lehin na awa na o ni ibimo. Na hanyate hanyamāne śarīre (BG 2.20). Imoye to rorun. Nitoripe awa je nkankana pelu Krsna. Ton ba bi Krsna, lehin na won mabi emi na. Ti Krsna o ba ni ibimo, lehin na emi na o le ni ibimo. aja ni Krsna je, beena aja ni wa. Ajam avyayam Kṛṣṇa o le paari, owa tayeraye. Awa na le wa tayeraye, nitoripe nkankana laje pelu Oluwa. Beena kilode ti awon apa nkankana se wa nibe? Kilode t'owo mi se wa nibi? Nitoripe moni ilo fun. Moni lati lo owo mi, moni lati lo ika owo mi. O se pataki. Awon asiwere wanyi won sowipe, " Kilode t'Oluwa se dawa saye yi?" Asiwere, nitoripe o se pataki. Nitoripe Oluwa loje, O si fe ke sise fun. Gege bi okurin pataki, oni awon iranse to po. Ti asiwere kan ba bere, " Kilode teyin se ni awon iranse to po bayi?" " Nitoripe Okurin pataki nimi, mosi fe bee!" Imoye to rorun. Beena, T'Oluwa baje olori to gaju, lehin na ole ni iranse to po bose fesi. Bibeko bawo losefe sise?