YO/Prabhupada 0644 - Everything is there in Krishna Consciousness



Lecture on BG 6.1 -- Los Angeles, February 13, 1969

Prabhupada: Ise sise?

Olufokansi: Ise idaraya.

Olufokansi: Iru akoko idaraya ni awon eyan ninu imoye Krsna lese?

Prabhupada: Akoko idaraya?

Olufokansi: Beeni.

Prabhupada: Ijo ( Erin) Ewa ke bawa jo. Se ere idaraya ko niyen? toba de ti reyin e je prasadam. Seyin tunfe s'ere ju bayi lo? Kini idaun yin. Se ere idaraya ko niyen?

Olufokansi: Beeni. mosi rowipe o le gan fun eni to wa lati...

Prabhupada: Kilo le nibe? Ijo jijo je nkan to le? Ke korin ke jo?

Olufokansi: O rorun fun awon ton gbe ninu ile-ajosin na.

Prabhupada: Oh, bi iwo na se wa awon elomi na le wa. Gbogbo eyan lowa. Awa o bere owo kankan fun ijo jijo yi. Eyin ma losi ile ijo sugbon eyin man sonwo. Sugbon aw o bere owo kankan. Awon akeko wanyi kan toro nkan die lowo yi nitoripe agbodo toju ara wa. Awa o le gba owo kankan lowo yin. Beena teyin ba wa ke jo, fun ere idaraya yi, nkan to da leleyi. Gbogbop nkan lo wa ninu imoye Krsna yi. Afe orin, orin wa nibi. Afe jo, oji wa n'bi. Ele mu awon irinse orin yin, ele paraapo. Awa sin pin awon ounje to da. Beena ilana fun ere idaraya ni ise yi je. (Erin) Beeni. Teyinba rowipe eyin ma wa iru ilana yi, kosi ise kankan. ere idaraya nikan. Su-sukham (BG 9.2). Wanti salaaye ninu Bhagavad-gita ninu apa iwe kesan eyin ma ri nibe, su-sukham - gbogbo nkan wanyi dara gan. Eyin le sewaadi ninu ilana wa ke wo boya isoro kankan wa nibe. E sofunmi, seyan kankan wa. " Isoro ni kokooro yi je." E ma bere sini jiyan. Nkan to dara leleyi. Ere idaraya. Otan. E kan sofunmi " Swamiji, nkan bayi bayi ere idaraya ko lejo." Kosi nkankan. Nkan ti awon eyan fe niyen. Nkan adayeba leleyi, gege bi awon omode. Nigbaton ba ri awon omo okurin at'obirin ton jo, awon omode na ma bere sini jo. Lesekese. Nkan toma sele lesekese niyne, ile aye yi. Bi aye wa seri niyen ninu odo metalokan. Kosi isoro kankan. Aweon eyan ton jo ton korin ton jeun. Otan. Kosi ile ise konkon, kosi ise kankan, kosi ile-eko ero giga. Ko wulo. Awon nkan eke ni awon nkan wanyi. Ānandamayo 'bhyāsāt, (Vedānta-sūtra 1.1.12) Vedānta sowipe gbogbo eda laye yi, anadamaya l'Oluwa je, to kun fun igbadun ati idunnu, awa si je nkankana pel'Oluwa, amuye kanna la ni. Ānandamayo 'bhyāsāt. Beena gbogbo ilana wa yi ni lati paarapo pelu anandamaya, Krsna, ninu ijo idaraya re. Nkan toma je ki inu wa dun niyen. NIbi awa fe ki inu wa dun pelu awon ona eke. Ibanuje de ti mu wa. Sugbon teyin ba ni imoye Krsna, teyin ba ji ipo yin talakoko soke, idunnu, Ānandamayo 'bhyāsāt. Awon oro Vedanta leleyi. Nitorip anandamaya ni'wa gbogbo wa. Nkan ti gbogbo awon eyan sewaadi lati ri niyen. Ni La Cienega Avenue yi, awon ile-ounje to wa po gan, awon aami orisirisi. kilode? Wan polowo. " E wa sibi, ananda wa nibi, igbadun wa nibi." On polowo, nkan t'awa na n'se niyen. " Ananda leleyi." Beena gbogbo wa lan wa ananda, tabi igbadun. Sugbon ipo orisirisi igbadun lowa. Nkankana. Elomi lema gbiyanju lati wa igbadun yi lati ipo ile aye yi, elomi le ma gbiynaju lati wa igbadun yi lati irori, imoye, oriki, tabi aworan. elomi lema gbiyanju lati wa igbadun yi lori ipo to gaju. Gbogbo wa lan gbiynaju lati wa igbadun yi, Ise kan soso tani niyen. Kilode teyin sise gan lataaro daale? Nitoripe e mowipe, laale, " Mole ni asepo pelu omo-obirin bayi bayi" tabi " Mole ni asepo pelu iyawo mi, mole gbadun." Gbogbo wa lan gba isoro orisirisi s'ara lati le ni igbadun yi. Igbadun ni afojosun to gaju. Sugbon awa o mo ibi ti'gbadun yi wa. Itanraeni towa niyen. Igbadun gidi wa ninu irisi togaju pelu Krsna. Eyin ma ri wipe nigbogbo'gba ni inu Krsna dun. Awon aworan po tele wo. T'awa basi paarapo pelu re, awa na ma ni idunnu yi, otan. Seyin ti ri aworan Krsna kankan ton sise pel'ero? ( Erin) Ero nla? Tabi seyin ti ri aworan kankan ton fa siga? ( Erin) Idunnu wa lara re, se ri bayi? Idunnu. Beena teyin bafe sewaadi nipa ara yin, e sewaadi tole funyin ni idunnu. To kunfun igbadun nikan. Ānandamayo 'bhyāsāt (Vedānta-sūtra 1.1.12). Igbadun lasan. Kos'ona eke kankan. Ānanda-cinmaya-rasa-pratibhāvitābhiḥ. IEyin ma ri ninu Brahma-saṁhitā

ānanda-cinmaya-rasa-pratibhāvitābhis
tābhir ya eva nija-rūpatayā kalābhiḥ
goloka eva nivasaty akhilātma-bhūto
govindam ādi-puruṣaṁ tam ahaṁ bhajāmi
(Bs. 5.37)

Ānanda-cinmaya-rasa. Itowo nitumo Rasa, oun to dun ninu. Gege b'awa se feran lati je adun, awon nkan to dun, ounkoun. Kilode? Nitoripe odun lenu. Beena gbogbo wa lan gbiynaju lati ni itowo yi lati gbogbo nkan. Afe gbadun imo ako ati abo. Itowo wa nibe. Beena nkan ton pe ni adi- itowo niyen. Beena awon itowo to po gan wa. Ninu Brahma-saṁhitā, ānanda-cinmaya-rasa. Itowo aye yi, teyin ba towo, lesekese loma tan. Lesekese loma tan. Iseju kekere. Kasowipe eyin ni adun to dun gan. Teba towo. " Oh, o dun gan." " Ema tun mu imi." " A da." "Imi?" " Rara mio fe mo, o tito. Seri bayi? Beena itowo aye ma tan. Kole wa tayeraye. Sugbon itowo gidi ma wa tayeraye. teyin ba towo, eyin ma tun towo, kole tan. Ānandāmbudhi-vardhanam. Caitanya Mahāprabhu sowipe, " Itowo yi a ma posi." Botilejpe bi omi okun lose ri, ton posi. Seyin ti ri omi okun. Ko l'opin. Omi okun Pacific sin posi, sugbon kole kun. To ba kun isoro nla loma sele, seri bayi? Sugbon pel'ofin osweda, pel'ase Oluwa, kole koja aye e/ Om duru sibi toye. Sugbon Caitanya Mahāprabhu sowipe omi okun igbadun, igbadun giga yi, sin posi

Ānandāmbudhi-vardhanaṁ prati-padaṁ pūrṇāmṛtāsvādanaṁ
sarvātma-snapanaṁ paraṁ vijayate śrī-kṛṣṇa-saṅkīrtanam
(CC Antya 20.12, Śikṣāṣṭaka 1)

Eyin ma ri eleyi gba teyin ban korin Hare Krsna, igbara idunnu teyin ma posi,posi, posi.