YO/Prabhupada 0721 - You Cannot Imagine God. That is Foolishness
Arrival Address -- Los Angeles, February 9, 1975
eyin o le mo nipa Krsna pelu ona imi - jnana, yoga, tapasya, karmi, tabi ebo, tabi saraka. KIole ye yin. Krsna sowipe bhaktyā mām abhijānāti. teba fe mo Krsna boseje, egbodo tele ilana yi, to rorun gan, man-manā bhava mad-bhakto mad-yājī māṁ namaskuru (BG 18.65): " E ronu mi nigbogbo igba, e s'aadura simi, e teriba funmi." Nkan merin. Ekorin Hare Krsna. Ironu Krsna niyen, man-mana. afi teyin baje olufokansi kosi besele lo asiko yin bayi. Lehin na teba korin Hare Krsna maha-mantra, lesekese lema d'Olufokansi. E s'adura si awon irisi Olorun. Afi teyin ba je olufokansi, kosi besel saadura si Krsna.
Awon alainigbagbo ma sowipe, " Won s'adura si sigidi." Rara. Iro niyen je. Awon eyan yi o mo eni ti Krsna je; On gba ise awon olufokansi l'ona tawa le gba lati sise fun. Ti Krsna ba fi virat-rupa fi han, kosi basele sise fun. Nib leti fe ri aso fun virat-rupe? gbogbo aso ninu aye yi gan kole to. (Erin) Nitorina ni Krsna se di ere tio ju apa merin lo, bayi a le wa aso fun. Ele toju Krsna pelu nkan teni. Ore-ofe re niyen. Nitorina ewo loje, arcye viṣṇu śilā-dhīḥ (Padyāvalī 115). ti awon oni ranu ba rowipe irisi Visnu je okuta tabi igi lasan: vaiṣṇave jāti-buddhiḥ, tabi awon olofokansi wa lati ilu kan, nārakī-buddhi. (Isinmi) Awa o gbodo se. Otooro niwipe Krsna wa nibi. Pelu ore-ofe re lose wa ninu irisi yi kin ba le ri; Okuta ko loje. Toba tie je okuta, Krsna na niyen, nitoripe kosi nkan imi afi Krsna. Laisi Krsna kole s'aaye mo. Sarvaṁ khalv idam brahma (Chāndogya Upaniṣad 3.14.1). Beena Krsna gan si lagbara toba tie je okuta Ole gba ise teba se fun. Krsna niyen.
Gege na egbhodo ni oye nipa awon nkan wanyi, teba si ni oye nipa Krsna dada, eleyi gan tito lati je ke pada si odo metalokan laaye yi.
- janma karma me divyaṁ
- yo jānāti tattvataḥ
- tyaktvā dehaṁ punar janma
- naiti mām eti kaunteya
- (BG 4.9)
Wanti salaaye nibi. Afi pelu ise ifarasi Krsna lale ni oye nipa Krsna, ko s'ona imi. Eyin o le ro iroku ro. " Boya bayi ni Krsna se je." Gege bi awon Mayavadi, ti won fori ro. Ironu wanyi o le ran yin lowo. Eyin o le fori ro nkan t'Olorun je. Iranu niyen. Olorun ju ironu yin lo. Bibeko kole je Olorun. Kilode to ye ko wa ninu nkan teyin fori ro?
Agbodo ni oye nipa awon nka wanyi dada, teya ba d'Olufokansi lole ni oye dada. Bibeko rara. Nāhaṁ prakāśaḥ sarvasya yoga-māyā-samāvṛtāḥ (BG 7.25): "Mio le farahan si gbogbo eyan." Kilode toma farahan si gbogbo eyan? Ti inure ba dun a farahan si yin. Sevonmukhe hi jihvādau svayam eva sphuraty adaḥ (Brs. 1.2.234). Eyin o le so f'orun ko jade, lesekese. Ti inu re ba dun a ran laaro. Beena, egbodo jeki inu Krsna dun, asi farahan si yin, a bayin soro asi fun yin ni bukun.
Ese pupo.
Olufokansi: Jaya! Ogo fun yin!