YO/Prabhupada 1057 - Oruko miran fun Bhagavad Gita ni Gitopanisad, koko oro imoye Veda
660219-20 - Lecture BG Introduction - New York
Prabhupāda
- oṁ ajñāna-timirāndhasya
- jñānāñjana-śalākayā
- cakṣur unmīlitaṁ yena
- tasmai śrī-gurave namaḥ
(Mo fi ọwọ fun olukọni mi pẹlu itẹriba. ti o si la oju mi ninu okunkun biribiri aimọkan pẹlu ògùṣọ imọ.)
- śrī-caitanya-mano-'bhīṣṭaṁ
- sthāpitaṁ yena bhū-tale
- svayaṁ rūpaḥ kadā mahyaṁ
- dadāti sva-padāntikam
(Nigbawo ni Śrīla rūpa Goswami Prabhupāda ti o ti se eto isẹ ninu aye yi lati se ifẹ ti Oluwa Caitanya yio fi mi si aabo labẹ ẹsẹ ojuoro rẹ, Mo fi ọwọ ati itẹriba se dọbalẹ si ẹsẹ oloju-oro olukọ mi ati si ẹsẹ gbogbo awọn olukọni ni ọna ise Oluwa.)
- vande 'haṁ śrī-guroḥ śrī-yuta-pada-kamalaṁ śrī-gurūn vaiṣṇavāṁś ca
- śrī-rūpaṁ sāgrajātaṁ saha-gaṇa-raghunāthānvitaṁ taṁ sa-jīvam
- sādvaitaṁ sāvadhūtaṁ parijana-sahitaṁ kṛṣṇa-caitanya-devaṁ
- śrī-rādhā-kṛṣṇa-pādān saha-gaṇa-lalitā-śrī-viśākhānvitāṁś ca
(Mo fi ọwọ ati itẹriba se dọbalẹ fun gbogbo awọn Vaisnava ati fun awọn Gosvami mẹfa, ati Śrīla Rūpa Gosvāmī, Śrīla Sanātana Gosvāmī, Raghunātha dāsa Gosvāmī, Jīva Gosvāmī pẹlu gbogbo awọn alabasepọ wọn. Mo fi ọwọ ati itẹriba se dọbalẹ fun Śrī Advaita Ācārya Prabhu, Śrī Nityānanda Prabhu, Śrī Caitanya Mahāprabhu, ati awọn ọmọ lẹhin Rẹ, ti Śrīvāsa Ṭhākura jẹ olori wọn. Mo fi ọwọ ati itẹriba se dọbalẹ fun Oluwa Ọlọrun Śrīmatī Rādhārāṇī ati gbogbo awọn gopi, pẹlu Lalita ati Visakha ti wọn jẹ olori wọn.)
- he kṛṣṇa karuṇā-sindho
- dīna-bandho jagat-pate
- gopeśa gopikā-kānta
- rādhā-kānta namo 'stu te
(Krishna Ọlọrun mi ọwọn, Iwọ ni ọrẹ awọn onipọnju ati orisun isẹda aye. Iwọ ni Oluwa awọn olusọagutan ati Ololufẹ Rādhārāṇī. Mo fi tọwọtọwọ se itẹriba fun Ọ.)
- tapta-kāñcana-gaurāṅgi
- rādhe vṛndāvaneśvari
- vṛṣabhānu-sute devi
- praṇamāmi hari-priye
(Mo bọwọ mi fun Rādhārāṇī, ti awọ ara rẹ dabi dídà wura ti o si jẹ Iyalode Vrndavana. Ọmọbinrin ọba Vṛṣabhānu, oloju ẹgẹ Oluwa Ọlọrun.)
- vāñchā-kalpatarubhyaś ca
- kṛpā-sindhubhya eva ca
- patitānāṁ pāvanebhyo
- vaiṣṇavebhyo namo namaḥ
(Mo fi ọwọ ati itẹriba se dọbalẹ fun gbogbo jọsin Vaishnava ti Oluwa. Wọn le se imusẹ ifẹ ti gbogbo eniyan, gẹgẹ bi igi onibuọrẹ, bẹ ni wọn si kún fun aanu fun awọn alabuku ẹda.)
- śrī-kṛṣṇa-caitanya
- prabhu-nityānanda
- śrī-advaita gadādhara
- śrīvāsādi-gaura-bhakta-vṛnda
(Mo bọwọ mi fun Śrī Kṛṣṇa Caitanya, Prabhu Nityānanda, Śrī Advaita, Gadādhara, Śrīvāsa ati gbogbo awon olufokansi t'Oluwa Caitanya.)
- hare kṛṣṇa hare kṛṣṇa kṛṣṇa kṛṣṇa hare hare
- hare rāma hare rāma rāma rāma hare hare
(Oluwa mi, ati agbara mimọ Oluwa, Ẹ jọwọ Ẹ fimi sinu isẹ yin. Isẹ ile aye yi ti sumi. Ẹ jẹ ki njisẹ yin.)
Ọrọ àsọsàju iwe mimọ Gītopaniṣad, Bhagavad Gita Bi O Se Jẹ ti A.C Bhaktivendanta Swami, Ẹni ti o kọ iwe Srimad- Bhagavatam, Irin ajo to rọrun si awọn aye ọrun miran, Olootu fun Yipada s'Oluwa, ati bẹ bẹ lọ.
Bhagavad Gita tun jẹ mi mọ bi Gītopaniṣad. O jẹ koko imọ ilana Vediki. o si jẹ ọkan ninu awọn Upaniṣads ti o wa ni pataki julọ ninu iwe Vediki. Ọpọlọpọ awọn iwe asọye ni ede Gẹẹsi ni o wa lori Bhagavad Gita yi a si le salaye kini idi rẹ ti ani lati se atúnse miiran ni ede gẹẹsi ni ọna ti o tọ-lẹhin Ikini... Iyaafin Charlotte Le Blanc ọmọ orilẹ ede Amerika kan ni o beere lọwọ mi lati se ifilọ itumọ iwe mimọ Bhagavad Gita kan ni ede Gẹẹsi ti o le ka . Dajudaju ni orilẹ ede Amerika ọpọlọpọ awọn itọsọna Bhagavad-gita ni wọn wa ni ede Gẹẹsi, sugbọn ni iwọn ti mo ti ri, ki ise ni Amerika nikan sugbọn ni India na, ko si ọkan ninu wọn ti a le wipe o daju, nitori o fẹrẹẹjẹpé ninu gbogbo ikọkan wọn ni olutumọ ti sọ ero ara rẹ ninu awọn asọye lori Bhagavad-gita lai fẹnu kàn ẹmí ti iwe mimọ Bhagavad gita gẹgẹ bi o se jẹ.
Ẹmí ti iwe mimọ Bhagavad Gita wa ni imẹnuba ninu Bhagavad-Gita funrarẹ.
Bayi lose ri: Ti a ba fẹ mu oogun kan a ni lati tẹlẹ awọn ilana ti wọn kọ sori aami. A ko le mu oogun gẹgẹ bi o se wu wa tabi lori imọran ti ọrẹ kan. Sugbọn o gbọdọ jẹ gẹgẹ bi o ti wa lori aami tabi lori imọran ti ologun ti fun lasẹ ni a ma mulo. Bákan náà, o yẹ ki a gba iwe mimọ Bhagavad-gita bi asafọ rẹ ti da nimọran Funra Rẹ.