YO/Prabhupada 1069 - Awon esin aye isin man soro nipa igbagbo. Igbagbo awon eyan le yipo - sugbon Sanatana dharma o le yipo

Revision as of 00:30, 14 June 2018 by Vanibot (talk | contribs) (Vanibot #0019: LinkReviser - Revised links and redirected them to the de facto address when redirect exists)
(diff) ← Older revision | Latest revision (diff) | Newer revision → (diff)


660219-20 - Lecture BG Introduction - New York

Ẹsin loye si ero igbagbọ, bẹni igbagbọ si le yipada. eyan le yipo - sugbon Sanatana dharma o le yipo Nitorina, sanatana-dharma, bi a se salaaye tẹle, pe Oluwa jẹ sanatana, ati ibugbe imolẹ, ti o leri isalu ọrun, eyini na jẹ sanatana. Awon eda alaaye, sanatana na ni awon na. apapọ isepọ ti Oluwa Atobiju ati awọn ẹda alãye ni ibugbe sanatana ni asepe ti aye ọmọ eniyan. Oluwa ni oju-anu pupọ fun awọn ẹda alãye nitori wọn jẹ ọmọ Rẹ. Oluwa Ọlọrun kéde ninu Bhagavad Gita sarva-yoniṣu kaunteya sambhavanti mūrtayo yāḥ (BG 14.4). Gbogbo awon eda.. gbogbo oni ruru awọn ẹda alãye ni wọn wa nibẹ ni ibamu pẹlu orisirisi karmas wọn, sugbọn nibi Oluwa funrarẹ sọ wipe Oun ni baba gbogbo wọn Nitorina ni Oluwa se sọkalẹ lati se irapada gbogbo awọn ti wọn ti kọsẹ wọnyi, awọn ẹmi ninu ide pè wọn pada si ọrun ayeraye sanatana ki awọn ẹda alãye sanatana le ri ipo wọn ayeraye sanatana gba pada ni sepọ pẹlu Oluwa ni aye ainipẹkun. Oluwa nwa funraRẹ ni orisirisi awọn ifarahan bi ẹda, tabi ki o rán awọn iranṣẹ rẹ ti o gbẹkẹle bi ọmọkunrin tabi awọn igba keji Rẹ tabi awọn ācāryas lati se irapada awọn ti wọn wa ninu ide.

Nitorina, sanatana-dharma ko se tọka si ilana ẹgbẹ ẹsin kankan. O jẹ iṣẹ ayeraye ti iye ainipẹkun awọn ẹda alãye ni ibasepọ pẹlu Oluwa Atobiju, Ọkan titi aye ainipẹkun. Bi a ti sọ tẹlẹ, sanatana- dharma ntọkasi ojúṣe ayeraye ti awọn ẹda alãye. Śrīpāda Rāmānujācārya ti salaye sanatana funni gẹgẹ bi "eyi ti kò ni ibẹrẹ tabi opin," nitorina nigba ti a ba sọrọ nipa Sanatana-dharma, a gbọdọ gbà bi otitọ lori aṣẹ ti Śrīpāda Rāmānujācārya wipe ko ni ibẹrẹ tabi opin Ẹsin ni ede gẹẹsi yatọ diẹ si itumọ sanatana-dharma. Ẹsin loye si ero igbagbọ, bẹni igbagbọ si le yipada. Eniyan le ni igbagbọ ninu ilana kan pato, àni o si le yi igbagbọ rẹ pada ki o si gba imiran, sugbon sanatana-dharma ntọkasi aṣayan iṣẹ-ṣiṣe eyi ti ko le yipada. Fun apẹẹrẹ, a ko le ya sisan omi kuro lara omi, Oru ati ina. Tabi ki a ya ooru kuro ninu ina. Bakanna, ni a ko le ya iṣẹ ayeraye ti awọn ẹda alãye ainipekun kuro lara wọn. Ko se yipada. A gbọdọ se iwari ipa ti ko le se mani fun ẹda alãye kọọkan. Nigba ti a ba sọrọ nipa sanatana-dharma, nitorina, a gbọdọ gba bi otitọ lori aṣẹ ti Śrīpāda Rāmānujācārya wipe ko ni ibẹrẹ tabi opin. Eyi ti kò ni opin tabi ibẹrẹ kò gbọdọ jẹ iyapa-isin, nitoripe odi kan ko le se lopin. Ti a ba se apejo lori sanatana-dharma, Awọn ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ ẹsin ẹlẹgbẹ-nsẹgbẹ yoo ṣi ro lasanlasan pe sanatana-dharma na jẹ iyapa-ẹsin. ṣugbọn ti a ba lọ jinna sinu ọran na ki a si ro o loju imọlẹ ti imọ igbalode, o ṣee ṣe fun wa lati ri pe sanatana-dharma ni owo ti gbogbo awọn eniyan araye - rara, ti gbogbo awọn ẹda agbaye. Ẹsin igbagbọ ti kii se sanatana le ni ibẹrẹ ninu ọjọ itan awọn eniyan, ṣugbọn itan sanatana-dharma ko ni ibẹrẹ, nitoripe o ti wa pẹlu awọn ẹda alãye titi ayeraye. Ni eyi ti o fi kan awọn ẹda alãye, awọn iwe mimọ śāstras alasẹ sọ fun wa pe ko si ibimọ tabi iku fun ẹda alãye. O ti wa ni mẹnuba ninu Gita wipe ko si ibimọ fun ẹda alãye bẹni ko si nku. O jẹ ainipẹkun bẹni ko le ni iparun, o si maa tẹsiwaju ninu igbe si aye lẹhin iparun ti ibùgbé awọ ara rẹ.