YO/Prabhupada 1080 - Isonisoki ti Bhagavad-gita - Oluwa ni Krishna. Oluwa fun awon egbe eyan kan soso ko ni Krishna je

Revision as of 13:13, 21 September 2017 by Vanibot (talk | contribs) (Vanibot #0005 edit: add new navigation bars (prev/next))
(diff) ← Older revision | Latest revision (diff) | Newer revision → (diff)


660219-20 - Lecture BG Introduction - New York

Isonisoki Bhagavad-gita - Ọlọrun kan ti o wa ni Krishna. Krishna ki ise Ọlọrun fun egbe ipinya. Oluwa kede ni gbangba ninu ìka kẹhin ti Bhagavad gita :

mala-nirmocanaṁ puṁsāṁ
jala-snānaṁ dine dine
sakṛd gītāmṛta-snānam
saṁsāra-mala-nāśanam
(Gītā-māhātmya 3)

Oluwa gba gbogbo ojuse. Fun ẹni ti o ba fi ara rẹ fun u, Oluwa gba gbogbo ojuse, O si se igbẹkẹle fun iru eniyan bẹ lori ẹsan ere gbogbo ẹṣẹ.

gītā su-gītā kartavyā
kim anyaiḥ śāstra-vistaraiḥ
yā svayaṁ padmanābhasya
mukha-padmād viniḥsṛtā
(Gītā-māhātmya 4)

"Eyan le se imọ-toto ara rẹ lojoojumọ nipa fifi omi wẹ, ṣugbọn ẹni ti o ba wẹ lẹẹkan soso ninu omi mimọ odo Ganga ti Bhagavad Gita, fun oluwarẹ idọti ode aye ti ni ibori patapata." Gītā su-gītā kartavyā kim anyaiḥ śāstra-vistaraiḥ yā svayaṁ padmanābhasya mukha-padmād viniḥsṛtā. Nitoripe Ẹni Isaju Eledumare funra Rẹ ni o sọ ọrọ inu Bhagavad Gita, ko ni wulo ki awon eniyan ka iwe ilana Vediki miiran. Ohun ti a nilo nikan ni lati ma farabalẹ gbọ ati ki a si maa ka Bhagavad Gita deede, gītā su-gītā kartavyā... Dandan ni ki awon eyan gba ona yi Gītā su-gītā kartavyā kim anyaiḥ śāstra-vistaraiḥ. Nitoripe ni asiko tawayi, akitiyan aye asan ti gba awọn eniyan l’ọkan to bẹ ti ko se ṣee fun wọn lati ka gbogbo iwe ilana Vediki. Iwe mimo kan soso yi le sise na nitoripe oun ni koko oro gbogbo awon iwe Veda, ati paapa nitori ti o jẹ ọrọ ti Ẹni Isaju Eledumare sọ.

bhāratāmṛta-sarvasvaṁ
viṣṇu-vaktrād viniḥsṛtam
gītā-gaṅgodakaṁ pītvā
punar janma na vidyate
(Gītā-māhātmya 5)

Bi o ti wa ni owe: Ẹni ti o mu omi odo Ganga, ti ni igbala, kini ka ti sọ tẹni ti o mu didun inu ti Bhagavad-Gita? Bhagavad-Gītā ni aladun pataki ti inu Mahābhārata, Viṣṇu Oluwa Krishna ni Viṣṇu àtètèkọse. Viṣṇu-vaktrād viniḥsṛtam. Bhagavad Gita ti ẹnu Ẹni Isaju Eledumare jade Ati gaṅgodakaṁ, Ganga si ti olojubioro ẹsẹ ti Oluwa wa. Bhagavad Gita si ti ẹnu Ẹni Isaju Eledumare jade. Dajudaju, ko si iyatọ nibẹ laarin ẹnu ati ẹsẹ Ọlọrun Ọba, sugbọn lati inu iwadi laisi ojúsàájú a ti le mọyi pe Bhagavad Gita tilẹ tun se pataki diẹ ju omi odo Ganga.

sarvopaniṣado gāvo
dogdhā gopāla-nandana
pārtho vatsaḥ su-dhīr bhoktā
dugdhaṁ gītāmṛtaṁ mahat
(Gītā-māhātmya 6)

Bi maalu ni Gitopanisad se ri, ati Oluwa Ọlọrun, ti o gbajumọ bi olusọagutan, si nfunwara Maalu yi. Sarvopaniṣado. koko ọrọ ninu gbogbo awọn Upaniṣads, kan ri gẹgẹ bi Maalu, Oluwa Ọlọrun, ti o gbajumọ bi olusọagutan, si nfunwara Maalu yi. pārtho vatsaḥ. Arjuna on ri bi ọmọ-malu, su-dhīr bhoktā. Awọn ọjọgbọn ati awọn jọsin mimọ ni wọn si ni lati mu wara aladun yi. Su-dhīr bhoktā dugdhaṁ gītāmṛtaṁ mahat. Adun na, wara Bhagavad-gita, wa fun awọn jọsin alakọwe.

ekaṁ śāstraṁ devakī-putra-gītam
eko devo devakī-putra ev
eko mantras tasya nāmāni yāni
karmāpy ekaṁ tasya devasya sevā
(Gītā-māhātmya 7)

Nisin, oye ki gbogbo aye kẹẹkọ ninu Bhagavad-gita, ẹkọ na. Evaṁ śāstraṁ devakī-putra-gītam. iwe mimọ kan soso lo wa, iwe mimọ kan soso fun gbogbo araiye, fun gbogbo araiye, eyini ni Bhagavad-gita yi. Devo devakī-putra eva. Ki Ọlọrun kan wa fun gbogbo aye - Śrī Kṛṣṇa. eko mantras tasya nāmāni. ati orin kan, mantra kan, adura kan, kikepe orukọ Rẹ: Hare Kṛṣṇa Hare Kṛṣṇa Kṛṣṇa Kṛṣṇa Hare Hare, Hare Rāma Hare Rāma Rāma Rāma Hare Hare. Eko mantras tasya nāmāni yāni karmāpy ekaṁ tasya devasya sevā. Ise kan soso lowa lati sise fun Eledumare. Ti eniyan ba kẹkọọ Bhagavad-Gita, awọn eniyan yio si nitara gidigidi lati lati ni ẹsin kan, Ọlọrun kan, iwe mimọ kan soso, ati ojúṣe kan. Eyi ti ni isosoki ninu Bhagavad-gita. Ọlọrun kan kan soso yi ni Krishna. Krishna ki ise Ọlọrun fun ẹgbẹ ipinya, bi orukọ Krishna se jamọ... Bi a ti salaaye tẹlẹ, Krishna tumọ si idunnu to gaju lọ.