YO/Prabhupada 1057 - Oruko miran fun Bhagavad Gita ni Gitopanisad, koko oro imoye Veda

Revision as of 16:02, 26 March 2015 by YamunaVani (talk | contribs) (Created page with "<!-- BEGIN CATEGORY LIST --> Category:1080 Yoruba Pages with Videos Category:Prabhupada 1057 - in all Languages Category:YO-Quotes - 1966 Category:YO-Quotes - Le...")
(diff) ← Older revision | Latest revision (diff) | Newer revision → (diff)


Invalid source, must be from amazon or causelessmery.com

660219-20 - Lecture BG Introduction - New York

Prabhupada:

oṁ ajñāna-timirāndhasya
jñānāñjana-śalākayā
cakṣur unmīlitaṁ yena
tasmai śrī-gurave namaḥ

(Mo doobale fun oluko mimo mi, toti laa oju mi to fo pelu okunkun aimokan pelu atupa imoye.)

śrī-caitanya-mano-'bhīṣṭaṁ
sthāpitaṁ yena bhū-tale
svayaṁ rūpaḥ kadā mahyaṁ
dadāti sva-padāntikam

(Nigbawo ni Śrīla Rūpa Gosvāmī Prabhupāda, toti da egbe yi sile ton sise apinfunni lati fun Oluwa Caitanya ni itelorun,nigbawo lo ma funmi ni idaabo labe ese re?)

vande 'haṁ śrī-guroḥ śrī-yuta-pada-kamalaṁ śrī-gurūn vaiṣṇavāṁś ca
śrī-rūpaṁ sāgrajātaṁ saha-gaṇa-raghunāthānvitaṁ taṁ sa-jīvam
sādvaitaṁ sāvadhūtaṁ parijana-sahitaṁ kṛṣṇa-caitanya-devaṁ
śrī-rādhā-kṛṣṇa-pādān saha-gaṇa-lalitā-śrī-viśākhānvitāṁś ca

(Mo doobale si oluko mi ati gbogbo awon alakowe lona ise ifarasi Oluwa. Mo doobale si gbogbo awon Vaisnava ati si awon Gosvami mefa, ati Śrīla Rūpa Gosvāmī, Śrīla Sanātana Gosvāmī, Raghunātha dāsa Gosvāmī, Jīva Gosvāmī pelu gbogbo awon alabasepo won. Mo dobaale si Śrī Advaita Ācārya Prabhu, Śrī Nityānanda Prabhu, Śrī Caitanya Mahāprabhu, pelu awon olufokansin ton tele, ti Śrīvāsa Ṭhākura je olori won. Mosi dobaale si Oluwa Krsna, Śrīmatī Rādhārāṇī ati aawon gopi, peluu Lalita ati Visakha tonje olori won.)

he kṛṣṇa karuṇā-sindho
dīna-bandho jagat-pate
gopeśa gopikā-kānta
rādhā-kānta namo 'stu te

(Krsna taya temi, omi okun ore ofe, eyin l'ore awon ton ni ibanuje l'okan ati orisun aye yi. Eyin l'oga awon oluso maalu okurin ati ololufe awon gopi, Radharani ni pataki. Mo teriba si re.)

tapta-kāñcana-gaurāṅgi
rādhe vṛndāvaneśvari
vṛṣabhānu-sute devi
praṇamāmi hari-priye

(Mo teriba si Radharani, ti kikodi ara re dabi wura, tosi je ayaba Vrndavana. Iwo ni omo-obirin Oba Vrsabhanu, Oluwa si feran yin gan.)

vāñchā-kalpatarubhyaś ca
kṛpā-sindhubhya eva ca
patitānāṁ pāvanebhyo
vaiṣṇavebhyo namo namaḥ

(Mosi teriba si gbogbo awon Vaisnava olufokansi Oluwa. Won le fun gbogbo awon eyan oun ife okan won, gege bi awon igi ton le funwa ni ohun ife okan wa, won si kun fun aanu si awon eda ton ti wolule.)

śrī-kṛṣṇa-caitanya
prabhu-nityānanda
śrī-advaita gadādhara
śrīvāsādi-gaura-bhakta-vṛnda

(Mosi doobale si Śrī Kṛṣṇa Caitanya, Prabhu Nityānanda, Śrī Advaita, Gadādhara, Śrīvāsa ati gbogbo awon olufokansi t'Oluwa Caitanya.)

hare kṛṣṇa hare kṛṣṇa kṛṣṇa kṛṣṇa hare hare
hare rāma hare rāma rāma rāma hare hare

(Oluwa mi, ati agbara mimo Oluwa, edakun e fimi sinu ise yin. Ise ile aye yi ti sumi. E jekin sise fun yin.)

Oro isaaju si Gitopanisad ti A.C Bhaktivendanta Swami, Onkowe ti'we Srimad- Bhagavatam, Irin ajo to rorun si awon isogbe imi, olootu fun Yipada s'Oluwa, ati bayi bayi lo.

Oruko imi fun GItopanisad ni Bhagavad-gita, koko oro imoye Veda, ati ikan ninu awon Upanisad tose pataki ju ninu imoye Veda. Bhagavad-gita yi, awon asọye repete wa ninu ede geesi A le salaaye bayi lati mo idi fun asọye imi lori Bhagavad-gita ni ede geesi. Ikan... Obirin olugbe America kan, Charlotte Le Blanc si beere lowo mi kin juwe Bhagavad-gita kan ni ede geesi tole ka. Looto ni'le America aimoye awon orisirisi Bhagavad-gita to wa ni ede geesi, sugbon bi mose ri gbogbo won, ni America ni kan ko, ati India na, Kosi ikan kan ninu won to daju, nitoripe gbogbo won lon salaaye bose wun won ninu awon asọye lori Bhagavad-gita lai fowokan emi to daju ti Bhagavad-gita gege bose je.

Eto nipa emi Bhagavad-gita si n'be ninu Bhagavad-gita gan. Bayi lose ri. Teyin ba fe mu ogun, lehin na e gbodo tele ijuwe towa lori igo ogun na. Awa o le dede bere sini m'ogun na basefe, tabi b'ore wa se so funwa, sugbon agbodo m'ogun na gege b'on se juwe lori paali re tabi bi ologun se juwe.

Beena, Agbodo gba Bhagavad-gita gege bi eni to salaaye re se so.