YO/Prabhupada 1059 - Gbogbo wa lani ibasepo otooto pel'Olorun

Revision as of 16:31, 26 March 2015 by YamunaVani (talk | contribs) (Created page with "<!-- BEGIN CATEGORY LIST --> Category:1080 Yoruba Pages with Videos Category:Prabhupada 1059 - in all Languages Category:YO-Quotes - 1966 Category:YO-Quotes - Le...")
(diff) ← Older revision | Latest revision (diff) | Newer revision → (diff)


Invalid source, must be from amazon or causelessmery.com

660219-20 - Lecture BG Introduction - New York

Lesekese teyan ba d'olufokansi Oluwa, oma ni asepo gidi pel'Oluwa. Oro repete leleyi, sugbon loro die a le sowipe awon olufokansi ni ibasepo marun pelu Oluwa. Eyan leje Olufokansi lona jeje, tabi olofokansi ton sise, eyan leje olofokansi toje ore, eyan si le d'olufokansi toje ebi, tabi ololufe.

Beena olofokansi toje ore si Oluwa ni Arjuna je. Oluwa le d'ore siwa. Looto, irepo yi ati irepo ta mo ninu ile aye yi, iyato to po gan wa laarin won. Konsepe gbogbo wa la gbodo ni ibasepo kanna pel'Olorun. Onikaluku ni ibasepo to yato pel'Oluwa lati ise ifarasi Oluwa ni ibasepo yi ma jade. Lese tawayi, Oluwa nikan ko lati gbagbe, sugbon ati gbagbe ibasepo tayeraye tani pel'Olorun. Gbogbo awon eda, ninu aimoye awon eda, gbogbo won lon ni ibasepo orisirisi pel'Oluwa. Nkan ton pe ni svarupa niyen. Svarupa. pelu ilana ise ifarasi Oluwa eyan o le ji svarupa yi soke. svarupa-siddhi lonpe ipo yi, pipe ipo t'olofin ton'ikaluku. Beena olufokansi ni Arjuna je, nitoripe oni asepo pelu Oluwa bi Ore.

Nisin, wanti salaaye Bhagavad-gita fun Arjuna, bawo l'Arjuna se gba? Oye ka foju si. Wanti salaaye ninu apa kewa bi Arjuna se gba Bhagavad-gita yi . Gege bi:

arjuna uvāca
paraṁ brahma paraṁ dhāma
pavitraṁ paramaṁ bhavān
puruṣaṁ śāśvataṁ divyam
ādi-devam ajaṁ vibhum
āhus tvām ṛṣayaḥ sarve
devarṣir nāradas tathā
asito devalo vyāsaḥ
svayaṁ caiva bravīṣi me
(BG 10.12-13)
sarvam etad ṛtaṁ manye
yan māṁ vadasi keśava
na hi te bhagavan vyaktiṁ
vidur devā na dānavāḥ.
(BG 10.14).

Nisin, Leyin igba ti Arjuna gbo Bhagavad-gita lat'Oluwa Oti gba pe param brahma ni Krsna, Brahman to gaju. Brahman. Brahman ni awon eda, sugbon eda to gaju tabi Eledumare ni eda to gaju tabi Brahman to gaju. paraṁ dhāma. Itumo Paraṁ dhāma niwipe Oun ni ibi isinmi gbogbo nkan aye yi. ati pavitram. Mimo loje laisi idoti kankan nitumo Pavitram. wansin pe ni purusam. Onigbadun to gaju nitumo Purusam, śāśvatam, lati'beere nitumo śāśvata, oun l'eda talakoko; divyam, to wa ni pipe, devam, Eledumare; ajam, laini ibimo; vibhum, alagbara.

Nisin eyan le bere sini ni iyemeji pe nitoripe Arjuna j'ore si Krsna, nitorina, o le so iru awon oro bayi si ore re. Sugbon Arjuna lati yo iru awon isiyemeji wanyi kuro ninu okan awon eyan ton ka Bhagavad-gita, O si soro lori agbara awon olori. O sowipe Sri Krsna l'Olorun fun oun ni kan ko, Arujna, sugbon fun awon olori bi Nārada, Asita, Devala, Vyāsa. Awon eyan pataki ni awon eyan wanyi lori eto pinpin imoye Veda. Gbogbo awon acaryass no gba gbe. Nitorina Arjuna sowipe " Ounkoun toti sofunmi nisin, Moti gba bi ooto."