YO/Prabhupada 1059 - Gbogbo wa lani ibasepo otooto pel'Olorun
660219-20 - Lecture BG Introduction - New York
Olukuluku ni ibasepọ kan pato pẹlu Oluwa Ni kete bi eniyan ba di olufọkansi ti Oluwa, o si tun ni iyekan taara pẹlu Oluwa. Iyẹn jẹ koko-ọrọ lati fi aàpôn ye ṣugbọn laifa ọrọ gun a le sọ wipe, olufọkansi ni ibasepọ pẹlu Ẹní Isaju Eledumare ọkan ninu awọn iru ọna marun: Eyan le jẹ ẹlẹsin ni ọna ti ko fara han; Eyan le jẹ ẹlẹsin ni ọna to làpôn; Eyan le jẹ ẹlẹsin bi ọrẹ; Eyan le jẹ ẹlẹsin bi obi; Eyan le jẹ ẹlẹsin bi ajọṣepọ Ololufẹ.
Bẹni Arjuna ni ibasepọ pẹlu Oluwa gẹgẹ bi ọrẹ. Oluwa le di ọrẹ. Dajudaju ọrẹ yi ati ọrẹ ti a ri ninu ode aye ọgbun iyatọ wa laarin . Eleyi jẹ ọrẹ imọlẹ... Eyi ti ko le se see laarin gbogbo eniyan. Gbogbo eniyan ni wọn ni ibasepọ kan pẹlu Oluwa, ati iru ibasepọ na le waye nipasẹ sise iṣẹ Oluwa ni asepe. Sugbọn ni ipo aye ti a wa bayi, ki ise Oluwa-Ọlọrun nikan ni a gbagbe, a ti gbagbe bakanna iyekan ayeraye wa pẹlu Oluwa. Gbogbo alãye kọọkan, lati inu awọn ogunlọgọ, ọkẹ àìmọye ẹda alaaye, ikọọkan ni o ni iyekan ayeraye pato pẹlu Oluwa. Iyẹn ni a npe ni svarūpa. Nipa iṣẹ Oluwa, eyan le se sọji svarūpa na, ipo yi ni a si npe ni svarūpa-siddhi – asepé ti ipo idanida wa. Nítorí náà, Arjuna jẹ ẹlẹsin, o si wà ni igburo- Oluwa - Ọlọrun ni irẹpọ.
Bayi Bhagavad Gita ti wa ni alaye fun. Ati bawo ni Arjuna se gba? O yẹ ki o wa ni akiyesi. Ọna ti o fi gba ti wa ni apẹẹrẹ ninu ori kẹwa. Gege bi:
- arjuna uvāca
- paraṁ brahma paraṁ dhāma
- pavitraṁ paramaṁ bhavān
- puruṣaṁ śāśvataṁ divyam
- ādi-devam ajaṁ vibhum
- āhus tvām ṛṣayaḥ sarve
- devarṣir nāradas tathā
- asito devalo vyāsaḥ
- svayaṁ caiva bravīṣi me
- (BG 10.12-13)
- sarvam etad ṛtaṁ manye
- yan māṁ vadasi keśava
- na hi te bhagavan vyaktiṁ
- vidur devā na dānavāḥ.
- (BG 10.14)
Bayi, lẹhin ti o ti gbọ Bhagavad Gita l’ẹnu Eledumare, Arjuna wí pé O gba Krsna ni param brahma, Brahman to gaju. Brahman. Gbogbo alãye kọọkan ni Brahman, ṣugbọn alãye ti o tobi julọ, tabi Ẹní Isaju Eledumare, ni Alakoso-Brahman. Param dhāma tumọ si wipe Oun ni isinmi kẹhin tabi ibugbe ti ohun gbogbo; pavitram tumọ si pe Oun ni Ologo mimọ, ti kii dibajẹ nipa abawọn aye; O tun pe ni puruṣam, ti o tumọ si pe Oun ni Atobajaye; śāśvatam, śāśvata tumọ si lati atetekọse; ẹni adayeba; divyam, imọlẹ; Adi-devam, ipilẹsẹ Ẹní Isaju Eledumare; ajam, kabi yi osi; ati vibhum, atobijulọ.
Nisinyi eniyan le ro wipe nitori Krsna jẹ ọrẹ Arjuna, Arjuna nsọ gbogbo eleyi fun lọna apọnle, ṣugbọn, lati mu iru iyemeji yi kuro ninu ọkàn awọn onkawe ti Bhagavad Gita, Arjuna se itẹnumọ awọn iyin logo wọnyi ninu ẹsẹ ti o tẹle nigba ti o wi pe Krishna ti jẹ mi mọn bi Ọlọrun Eledumare nipa oun nikan kọ, Arjuna, sugbọn nipa awọn alasẹ bi Nārada, Asita, Devala ati Vyāsadeva. Awọn eniyan nla ni wọnyi ti wọn se itanka imọ Vediki kaakiri ni ọna ti gbogbo awọn ācāryas ti gba. Nitorina Arjuna sọ pe "Ohunkohun ti O wi de ibi ti a bọrọ de yi, Mo gbà wọn patapata ni pipe."