YO/Prabhupada 1063 - Funwa ni irorun lati ise ati abajade ise wa

Revision as of 09:45, 27 March 2015 by YamunaVani (talk | contribs) (Created page with "<!-- BEGIN CATEGORY LIST --> Category:1080 Yoruba Pages with Videos Category:Prabhupada 1063 - in all Languages Category:YO-Quotes - 1966 Category:YO-Quotes - Le...")
(diff) ← Older revision | Latest revision (diff) | Newer revision → (diff)


Invalid source, must be from amazon or causelessmery.com

660219-20 - Lecture BG Introduction - New York

Gege ninu aye tawa yi, awa n'gbadun ise wa, ijeere ise wa. Kasowipe onisowo nimi timo de ti sise gan pelu ogbon ori mi timo de ni owo to po ninu ile ifowo . Nisin emi ni onigbadun. Beena, hasowipe moti bere ise mi pelu owo to po, sugbon tin ba se ise ipadanu.. timo s'owo nu. Beena mon jiya. Beena, ni gbogbo ise aye yi awa sin gbadun, awa gbadun ijeere ise wa. Nkan ton pe ni karma niyen.

Beena awon nkan wanyi, isvara, jiva, prakrti, tabi Eledumare, tabi awon eda, ile aye yi, asiko tayeraye, ati awon ise orisirisi tani, wanti salaaye awon nkan wanyi ninu Bhagavad-gita. Nisn ninu awon nkan marun wanyi, awon eda, ile aye yi ati asiko, awon nkan merin wanyi wa tayeraye. Nisin ifarahan, ifarahan prakrti le wa fun igba die, sugbon eyin o wipe nkan eke loje. Awon alakowe ti sowipe ifarahan ile aye yi pe eke loje, sugbon imoye Bhagavad-gita sowipe, tabi imoye awon Vaisnava, won o gba ifarahan ile aye yi bi eke. Won gba pe gidi ni ile aye yi je, sugbon fub igba die lowa. gege bi sanmo sen kojo ti asiko omi ojo bafe bere, leyin igbati asiko omi ojo yi ba bere, awon ewe tuntun asi jade lori ibikibi, ale jerisi. Lesekese ti asiko omi ojo ba de tan, awon sanmo na ma paare. Nigbogbogba, ti awon ewe yi ba gbe tan, ile na ma yagan. Beena, fun asiko die ni ile aye yi wa. Toba ya o ma yewa, am mo, lati awon iwe Bhagavad-gita. Bhūtvā bhūtvā pralīyate (BG 8.19). Iseda yi ma farahan fun igba die leyin na, asi paare. Ise prakrit niyen. Sugbon tayeraye lon sise, nitorina tayeraye ni prakrti wa. Nkan eke ko loje. Nitoripe Oluwa ti gba pe, mama prakrti, " Prakrti Mi." Apareyam itas tu viddhi me prakṛtiṁ parām (BG 7.5). Bhinnā prakṛti, bhinnā prakṛti, aparā prakṛti. Agbara toya to imi t'Oluwa ni iseda aye yi je, ati awon eda, agbara Oluwa na lon je sugbon won wa paapo. Won wa paapo tayeraye. Beena Oluwa, awon eda, agbaye, iseda aye yi, ati asiko, tayeraye lon wa fun. Sugon nkan toku, karma, fun asiko die lo wa. Awon ibajade karma tabi ise wa le wa fun asiko to pe gan. Awa sin jiya tabi awa n'gbadun ibajade ise wa lati aimoye igba, sugbon a le jeki awon ibajade karma wa yika. Sugbon ogbon pipe niyen ma gba. Awa sin sise to po gan, sugbon oye ka mo iru ise wo loye ka se tole funwa ni irorun lati gbogbo ibajade ise wa. Wanti salaaye ninu Bhagavad-gita.

Nisin, imoye toje pipe ni ipo isvara. Ipo isvara, tabi Eledumare, imoye to gaju loje. awon jiva, tabi awon eda, tonje nkankan na pelu Eledumare, awon na daju. Awon eda daju. Prakrti ni awon eda yi je, agbara, won de ti salaaye wipe iseda aye yi pe prakrti na loje, sugbon laarin awon meejeji, prakrti kan, awon jiva, won daju. Prakrti keji o daju. Iyato to wa niyen. Nitorina ni jiva prakrti se gaju nitoripe won ni iru imoye t'Oluwa. Oluwa loni imoye to gaju. Awon eyan o gbodo fi awon eda lasan fi we Oluwa Rara. Awon eda aye yi kosi bonsele logbon to wa ni pipe ju ninu igbese aye won. Imoye iranu leleyi, Imoye iranu. Sugbon o daju. Otan. Sugbon oun ko lo daju ju.