YO/Prabhupada 0012 - Orisun imo gbodo je nipa ti gbigbo oro



Lecture on BG 16.7 -- Hawaii, February 3, 1975

Oni kaluku wa, ko si eni ti o da pepe. A pon oju wa le pupô: "Se o le fi han mi?" Kini agbeyô t'oju rè ni ti o fi le ri? Oun ko lero wi pe, pe "Emi ko ni agbeyô kan kan; mo si fè ri" Awon oju yii, ah, won ko ni omirira ti won, ise deede won fi ara ti awon orisirisi eto. Nisinyi o le riran, nitori wi pe ina ijôba wa nbè. Gèrè ti won ba ti mu ina lô, è ko le riran mô. Kini iyi oju rè ? Iwo ko le ri nkan ti ohun sele lèyin ogiri yi.

Nitori eyi ma se ni igbagbô ni ori awon oyé ti oju, imu, eti, ati ara rè le fi han è bi orisun imô. Orisun imô gbôdô jè ni pa ti gbigbô ôrô. Eyi la npe ni śruti. Nitorina orukô Vedas ni śruti. Śruti-pramāṇa, śruti-pramāṇa. Gègè bi ômôde tabi ôdômô kunrin ti o fè mô tani nse baba rè. Kini eri na ? Eri naa ni śruti, gbôrô lati ôdô iya rè. Iyà ni, " Baba rè ni yi" Bayi lo se gbô; ko ri bi o se di Baba rè. Nitori wipe, ki o to ni ara yii, Baba rè wa nibè, bawo lo hun sé lé rii? Nitorina ni pa riri, iwô ko léé sô èni ti onse Baba rè. O ni lati gbô lati ôdô alasé. Iyà ni alasé. Nitorina śruti-pramāṇa: gbigbô ni èri naa, ki isé riri. Riri... awon oju wa ti won o wa ni pi pé... Opôlôpô awon isoro lo wa nbè. Ni bakanna, ni pa iriri oju, è ko lé mô ododo.

Iwi ku wi ni iriri oju. Dokita Opôôlô. Dokita Opôôlô nsô iwi ku wi lori Okun Atlantiki O wa ninu kanga, kanga ti ofi èsè mèta jin ninu, ni igba naa ni ôrè rè kan wa fi ye wipe "Ah, emi ti ri ara omi nla" "Kini omi nla yi?" "Okun Altantiki ni" "Bawo lo se to bi to?" "O to bi gaan ni" Bayi ni Dokita Opôôlô se nro wipe, "Boya èsè mèrin ni. Esè mèta ni kanga yi. Boya èsè mèrin ni. O daa, èsè maarun. "Waa naa, èsè mèèwa" Ni bayi ni Dokita Opôôlô,se nwa awawi, sé o le gba ôna yi lati fi mô Okun Atlantiki tabi Okun Pasifiki? Sé è lé sé déndé gigun ati ibuu Okun Atlantiki, ati Pasifiki ni pa awawi? Nitori naa ni pa awawi, e ko lee mô. Nwon se awawi lati opolopo odun ni pa okun-aye yi, awon irawô méelo lo wa nbè, Kini gigun ati ibu, nibo ni... Ko si èni ti o mô nkan kan daju lori ile ayé yii, ka ma wa sô ni pa ti iselu ôôrun? Eleyi ju ojusé, ni ôna gbogbo.

Paras tasmāt tu bhāvo 'nyo 'vyakto 'vyaktāt sanātanaḥ (BG 8.20). E maa ri ni nu Bhagavad-Gita. Igbe aye miran wa. Eda ohunkohun yi, eyi ti è ri, ofurufu, ikoko ribiti, iyèn, eyi ti o ga ju yèn lo, awon ilera maarun ipilese lo tun wa. Eyi ni ibora. Gègè bi è sé ri agbôn. O ni ibora to le lèyin, omi si wa ninu eyi to fi bo nu. Bakanna, ninu ibora yi... Ati ode ibora na, awon ilera maarun tun wa, ti won ju ra won lô ni ègbè-gbèrun ôna. Ibora omi, ibora oyi, ibora inaa. Nitorina è ni lati wô inu awon ibora yi. Ni igba naa ni èyin o de ajoji ôôrun. Gbogbo ipinlè okun-aye yi, ni ailopin, koṭi. Yasya prabhā prabhavato jagad-aṇḍa-koṭi (Bs. 5.40) Jagad-aṇḍa tu mô si okun-aye. Koṭi, awon ègbèrun lôna egberun ti won so pô, iyen ni ile aye. Ni ikoja ilé ayé na ni isèda ôôrun, ofurufu miran. Ofurufu ni yèn naa. Iyèn ni a npé ni paravyoma. Nitori na ni pa iriri awon nkan ti a le ri, a ko lée se déende nkan ti o wa ni ori Osupa ta ti owa loorun ile aye yi, ninu ayeraye Bawo ni è se le mo idi ôôrun ni pa iwawi? I wa omugô le leyi.

Nitorina, awon iwe mimô sô wipé, acintyāḥ khalu ye bhāvā na tāṁs tarkeṇa yojayet. Acintya, oun aini tumô, toju ati mu o léé to, è ma sé gbi yanju lati ni oyée rè ni pa iéedi ati awiwi. Aigbôn le léyi. Ko sé sé. Nitori idi éyi, a gbô dô lo sodo Guru, oluko igbala. Tad-vijñānārthaṁ sa gurum evābhigacchet, samit-pāṇiḥ śrotriyaṁ brahma-niṣṭham (MU 1.2.12). Eyi ni ona naa.