YO/Prabhupada 0096 - A ni lati keeko lowo eni Bhagavata



Lecture on BG 13.4 -- Miami, February 27, 1975

Nkan ti mo nronu ni yi, "Omo Amerika, Omo India, Hindu, Musulumi," awon eyi je nkan egbin ninu okan mi. E we okan yin mo. Hṛdy antaḥ-sthaḥ abhadrāṇi. Awon ohun egbin wa ninu okan mi, bee ni ti a ba we okan wa mo, nigba na ni a o ni ominira ninu ipeloruko. Naṣṭa-prāyeṣu abhadreṣu nityaṁ bhāgavata-sevayā (SB 1.2.18). Naṣṭa-prāyeṣu. Awon ohun egbin won yi a di iwemo ti a ba nfi eti si Śrīmad-Bhāgavatam tabi Bhagavad-gītā ni deede. Nityaṁ bhāgavata...

Ati pe bhagavata tumo si iwe Bhagavata ati eni bhagavata. Eniyan bhagavata ni oluko igbala. Tabi eyikeyi olufokansin to je pataki. Oun ni bhagavata, maha-bhagavata, bhagavata. Bee ni bhagavata-sevaya ko tumo nikan si lati ma ka Bhagavad -Gita ati Bhagavavtam, sugbon a ni lati keeko lowo eni bhagavata. Iyen ni a beere fun. Chaitanya Mahaprabhu nimoran wipe, bhagavata para giya bhagavata-sthane: "Ti e ba fe lati ko Bhagavata, ki e si lo si odo eni Bhagavata ti o ti se aridaju nipa emi.

Ki se ti akosemose. Iyen ko le ran yin lowo. Eni osise akosemose - Mo lo si tempili, mo lo si ile ijo kan, mo si tun pada s'inu ipo orun apadi ti..., rara. E kan ni lati ma se pelu eni bhagavata ti o ni iye ti emi ara re daju. ki e si f"eti si iwe yi kanna lodo re, imo kanna. Asoju Olorun. Gege bi Olorun ti wi, tat samasena me srnu. Me srnu: "F'eti si Mi tabi asoju Mi. Igba na ni o le ni anfani."

Bee na ni a nsi awon ile ipâde yi sile lati fi anfaani fun awon eniyan ti won nse ponju. ko n se ni aye yi ni kan, ni aye ra ye.

ei rupe brahmanda bhramite kona bhagyavan jiva
guru-krsna-krpaya paya bhakti-lata-bija
(CC Madhya 19.151)

Bee na lo se je ojuse wa, a ti gba ise yi ni oruko Olorun. Olorun fun Ra Re wa lati ko wa. Bi O se fi iwe mimo Srimad Bhagavatam Re sile. O si fi si akoso awon iranse Re lati s'alaye fun awon eniyan ni apapo. A ngbiyanju lati se be. A o da ohunkohun to je titun kan sile tabi ti a ti ni ohunkohun ti ara wa. Awon dukia ati awon ohun ini na wa nbe. Awa o se ju ka ma pin won bi alaaru. Gbogbo e niyen.

A o si ni isoro kankan. Bi a ba ti le fi iwe Bhagavad Gita han, awon ilana Olorun, gege bi o se ri, nigba na ojuse wa pari. A o ni lati da ohunkohun sile; be ni a ko si ni agbara lati da ohunkohun sile. Gege bi awon opo miran. Won nda awon iru ero titun sile, iru eko titun..., gbogbo isokuso. Iyn ko le ran wa lowo. E gba imo gidi.