YO/Prabhupada 0097 - Emi o ju bi ofiwe ranse lo



His Divine Grace Srila Bhaktisiddhanta Sarasvati Gosvami Prabhupada's Appearance Day, Lecture -- Los Angeles, February 7, 1969

Ti a ba gbiyanju gidgidi lati ti egbe yi lo siwaju, nigba na, ti a ko, ti e o ba ni omo leyin, A dun mo Olorun ninu. Ati pe owo wa ni lati se ife Olorun. Iyen ni bhakti. Hṛṣīkena hṛṣīkeśa-sevanaṁ bhaktir ucyate (CC Madhya 19.170). Bhakti tumo si pe ka fi gbogbo ipa ara wa lati se itelorun. Igbesi aye tumo si itelorun fun ara re: Mo feran eyi. Mo feran eyi. Mo fe se nkankan. Mo fe ko orin kan, tabi kehu kan, je nkankan, tabi f'owo kan nkan, tabi to nkan wo. Eleyi jẹ, ohun kan, tumo si ... Ti o tumo si lilo ipa ara wa. Iyen ni igbesi aye yi. Mo fe f'owo kan ara to ro. Mo fe to iru nkan wo, kini won pe, ounje to dara. Mo fe gbo oorun bayi. Mo fe rin bayi." Ohunkanna - ririn, titowo, fifowokan, tabi ohunkohun - ni lati je lilo fun Olorun. Ko ju belo. Nipo ti a ba f'owo kan ohun miran, ti a ba fowo kan ese mimo olufokansin kan, fifowokan na a di wiwulo. Nipo ti a ma fi ma je ijekuje, ti a ba je Prasadam, iyen a se dédé. Nipo ti a ma fi gborun ohun miran, ti a ba gborun ododo ti a fi se ore fun Olorun... Be ni ko si nkan ti a da duro. Ti o ba fe lo ibalopo aye re, bee ni, o le lo lati fi se irugbin awon omo ti won se isokan Olorun. Ko si ohun ti a da duro. A kan so won di mimo. Ko ju yen lo. Eyi ni gbogbo eto na. Ko si oro pe "E feyi sile." Ka fi sile ko le see se. Bawo ni a se le fi sile? Ka gba pe eniyan ni mi. Ti enikan ba so wipe, "Ah, iwo ko le jeun", se o see se ni? Mo gbodo jeun. Ko si oro pe a ma fi jije sile. Ka so di mimo ni a beere. Bee na... imoye miran tun ni wipe, mo fe so wipe, ka fi agidi se. se l'ofo, bi won ti wi, "E kan di alaini ero kankan." Won se ni aroye. Dakun bawo ni mo se le di alail'ero? Ife gbodo wa nbe. Sugbon ma nife fun Olorun.

Be ni eyi se je ilana to dara. Ati paapa ti awon miran o ba fi se ni pataki, tabi ti won o ba wa si imoye wa, ti e ba fi se yanju, owo ni yen. A dun mo Olorun ninu. Awon asaju wa na o si ni itelorun, Guru Maharaja na o si ni itelorun. Ati yasya prasadad bhagavat... Ti awon ba ni itelorun, nigba na ise yin ti pari. Ki se pe awon miran na o ni itelorun tabi bèkô. Nipa kikorin yin awon eniyan die le ni itelorun - rara, iyen ko kan wa. O le telorun , o le ma telorun. Sugbo ti mo ba korin ni ona to ye, be ni awon arawàju mi, awon acaryas, won o ni itelorun. Owo mi ni yen, o pari, ti mi o ba da nkan te mi sile. Nitori na inu mi dun pupo pe Olorun ti se bukun mi pelu opolopo awon odomokunrin ati obinrin lati ran mi lowo. Ki ore ofe Olorun je ti yin ni ojo rere yi. Ko si ohun ti o je temi. Emi o ju bi ofiwe ranse lo. Mo njise fun yin ohun ti mo ti gbo lati odo Oluko Maharaja mi. T i eyin na ba si se bakanna, inu yi o si dun. Ile aye o si dun , inu Olorun a si dun, ati gbogbo nkan...