YO/Prabhupada 0099 - Bi Olorun se le da wa mo



Lecture on BG 13.4 -- Bombay, September 27, 1973

Bee ni, bi a se ri wipe orisirisi ipo eniyan lo wa, bi o ti le je wi pe gbogbo won wa ni Mumbai, tabi ilu kan miran. bakanna, gbogbo awon eda alaaye, won ki nse ti iwa kan na. Diẹ ninu wọn wa ni ifọwọkan pẹlu awọn ohun elo ti ipa ti awọn rere, diẹ ninu wọn wa ni ifọwọkan pẹlu awọn ohun elo ti ipa ti ife gidigidi, ati diẹ ninu wọn wa ni ifọwọkan pẹlu awọn ohun elo ti ipa ti aimokan. Bee ni awon ti won wa ninu aimokan, won da bi awon ti won subu sinu omi. Bi igbati ina ba bo s'omi, a ku patapata. Ati koriko gbigbe na, ti isàna ba ta sile, nipa anfani ti koriko gbigbe na, ina a jo. A si di ina pada.

Bakanna, awon ti won wa ni ipa rere, won le se idaji isokan Olorun won pelu irorun. Nitoripe iwe mimo Bhagavad Gita so wipe, yesam tv anta-gatam papam, Kilode ti awon eeyan o nwa si ile-ijosin yi? Nitoripe isoro to wa nibe nipe die ninu won wa ninu aimokan. Na mam duskrtino mudhah prapadyante naradhamah (BG 7.15). Won o le wa. Awon ti won kan ngbe igbesi aye elese won o le moyi isokan Oolrun yi. Iyen ko see se. Sugbon o je anfaani ti a fun olukaluku. A npon won le, "E joo e wa sibi. E joo..." Owo wa niyi loruko Olorun. Bi Olorun tikalararẹ wa lati kọ Bhagavad Gita-ti o si beere gbogbo eniyan, sarva-dharman parityajya mam ekam saranam vraja (BG 18.66) ise wa ni yen.

Nitorina Olorun mo yi pupo pupo, "Ah, awon eniyan yi nsise nitoti Mi. Mi o ni lati lo sibe. Won ti gba owo mi bi ise." Kini owo ti a ngba bi ise. A kan nbeere awon eniyan, "E jowo e fi ara yin fun Olorun." Nitori idi eyi awa je owon pupo. Olorun so wipe, na ca tasman manusyesu kascin me priya-krttamah (BG 18.69). Owo wa ni bi Olorun se le da wa mo.

Ko jo wa loju boya enikan yipada tabi beko ni isokan Olorun. Ojuse wa ni lati ponle, Ko ju yen lo. "Oga mi, e joo e wa, e wa wo aworan Olorun, e foribale, gba ounje ti a ti ya si mimo, e si pade sile." Sugbon awon eniyan o ngba. Kini idi eyi? Bayi, owo yi ko le see gbe soke nipa awon ti ti won kun fun ese.

Nitorina Olorun so wipe, yesam tv anta-gatam papam. Eniti o ti pari patapata awon iwa buburu re. yesam tv anta-gatam papam jananam punya-karmanam. Tani eniti o le ni ominira ninu awon ise elese ? Eniti o ba nse ise rere nigba gbogbo. Ti e ba nfi igba gbogbo se awon ise rere, nibo ni aye ati ko iwa ese ? Nitorina ise rere to dara julo ni pipe oruko Olorun, Hare Krishna maha-mantra. Ti e ba fi gbogbo igba nse, Hare Krsna, Hare Krsna, Krsna Krsna, ti okan yin ba nfi gbogbo igba nse isokan si Olorun, nigba na ko ni si aye fun awon nkan miran lati wa sinu okan yin. Eyi ni ilana isokan Olorun. Kete bi a ba ti gbagbe Olorun, esu a wa nibe, yi o si ri yin mu lesekese.