YO/Prabhupada 0100 - Gbogbo wa jemo Olorun lati igba lailai



Lecture on SB 6.1.8 -- New York, July 22, 1971

Bee ni gbogbo wa jemo Olorun lati igba lailai. Ni akoko ti a wa yi o ti di igbagbe, tèmolè. Nitorina a ti wa nlero wipe a o ni ajose kankan pelu Olorun. Sugbon eyi ki se ododo. Nitori a je t'apa t'ese Olorun, ajose na wa fun ayeraye. A kan ni lati se ni soji . Iyen ni isokan Olorun. Isokan Olorun tumo si wipe... Niisinyi okan wa ti yato. Mo nlero wipe oomo India ni mi. Elomiran nlero wipe, "Omo Amerika ni mi. Enikan nlero wipe " Emi l'eyi, emi ni yen." Sugbon ero wa gangan ye ki o je pe "Emi je ti Olorun." Iyen ni isokan Olorun. "Ti Olorun ni mi." Ati ni ajose isokan Olorun, nitori Olorun wa fun gbogbo eniyan, nitorina emi na je ti gbogbo eniyan. E kan gbiyanju lati ni l'oye. Ni ile India, asa won ni wipe ti a ba fi omo obinrin kan s'aya fun odomo kunrin, be ni l'ori ile ede yin na, nibi gbogbo, asa kan na.; Gegebi omo iba-kan ba se ma pe obinrin na ni ""Anti." Nisinyi, bawo lo se di "Anti"? Nitoripe, ni ibatan pelu oko re. Saaju ki won to gbe ni iyawo, kii se "Anti", sugbon ni kete bi (o) ti jemo pelu oko re. omo egbon oko di arakunrin re. E gbiyanju lati ni oye apeere na. Bakanna, ti a ba se atunse ajose wa, tabi isedale ibatan wa pelu Olorun, ati bi Olorun se wa fun gbogbo eniyan, bee ni emi na di ti gbogbo eniyan. Iyen ni ife gidi ti gbogbo agbaye. Awon eke karohun-wi ife agbaye ko le wa mule ayafi ti a ba koko se imule ibatan wa pelu aringbungbun. Gege bi e se je awon omo Amerika. Kini idi e ? Nitoripe won bi yin sile yi. Bee ni omo Amerika miran je egbe omo orile-ede yin. sugbon ti o ba di nkan miran, nigbana ko si ibasepo kankan pelu omo Amerika miran. Bee ni a gbodo se atunse ijemo wa pelu Olorun. Nigba na ni ibeere egbe ara agbaye, idajo ododo, alaafia, asiki yi o wa. Bibeko, ko le see se. Aaye aaringbungbun ti sonu.. Bawo ni idajo ododo ati alaafia se la wa? Ko ni see se.

Nitorina ni iwe mimo Bhagavad Gita ti fun wa ni igbekale fun alaafia. Igbekale fun alaafia ni wipe a ni lati ni loye wipe Olorun nikan ni onigbadun. Gegebi ninu tempili yi, ipo aaringbungbun wa ni Olorun. Bi a ba nse ounje, o je fun Olorun, ki se ni idi ti ara wa ni se nse ounje. Nigbeyin, bi a tile ma je prasadam na, sugbon nigbati a ba nwa ounje, a ko nlero wipe a nse ounje fun ra wa. A nse ounje fun Olorun. Nigbati e ba jade lati lo se akojo, kii se wipe awon ti won wa ninu egbe ikede, pe won ni ire anfani eyikeyi fun ara won. Rara. Won nse ikojo, tabi won npin awon iwe, ni itori Olorun, fun sise awon eniyan ni isokan Olorun. Ati oye koye ti won ba ri nibe, ni won a lo fun Olorun. Nipa ona bayi, nigbati a ba ti nse iru ilana aye yi, ohun gbogbo fun Olorun, iyen ni isokan Olorun. Awon ohun kan na, ti a nse, ni a ni lati ma se. a kan ni lati yi okan wa pada, wipe "Mo nse fun Olorun, ki se fun ara mi." Ni ona yi, ti a ba se idagbasoke isokan Olorun, nigba na ni a ma wa si okan asebaye wa. Nigbana ni a ma ni idunnu.

Ayafi ti a ba pada si okan abinibi wa, bibeko a nse were ni iwon ki won. Gbogbo eniti ko ba nse isokan Olorun, o je ni ti a gbodo wo ni were. nitoripe o nsoro ni ipo ti ti ko lese nle, ti ko ni eyin ola. O ma pari. Sugbon awa, gege bi awon eda alaaye, a wa ni ayeraye. Bee ni owo ti ko lese nle ki se ti wa. Owo wa ye ki o je ailopin nitoripe awa na wa titi lailai. Owo ailopin na ni bi a se nsin Olorun. Gege bi ika yi se je ipa ara mi, sugbon owo ailopin ika na ni lati ma sin ara yi, o pari. Nibi, ko ni owo miran. Ati pe iyen ni ipo ilera ti ika na. Ti ko ba le sin gbogbo ara na, ipo alaisan ni yen. Bakanna, bi Olorun se je ainipekun; awa na si wa ti ti ayeraye. Nityo nityānāṁ cetanaś cetanānām (Kaṭha Upaniṣad 2.2.13). Eyi je awon imoran iwe mimo ti Vediki. Alayeraye atobiju ni Olorun Oba, Shree Krishna, a wa na si wa ni ayeraye. A ki nse atobiju; eni ti nforibale niwa. Nityo nityānāṁ cetanaś cetanānām. Oun ni atobiju eda alaaye, awa na si je awon eda alaaye ti won nforibale. Eko bahūnāṁ yo vidadhāti kāmān. Okan soso eda alaaye, okan ainipekun, Oun ni o nse akoso gbogbo ohun ini fun aimoye awon ayeraye. Eko bahūnām, ailonka awon eda alaaye. E ko le ka won. Bahūnām. Eleyi ni ajose wa. Nitorina gege bi ipa ati ese, a ni lati sin Olorun, ati lati ma je oluforibale. Oun se akoso awon nkan ini wa. Oun ni Baba Atobijulo. Eleyi ni aye to se deede ati ile aye ominira. Iru aye miran, to ju nipa isokan Olorun, ile aye elese ni yen.