YO/Prabhupada 0112 - Nipa abajade ohun kan ni a fi ndajo
Television Interview -- July 29, 1971, Gainesville
Oniifọrọwanilẹnuwo: Ejoo, ni Odun 1965 le wasi Orile-ede yi, bi mo ti so. lori ilana tabi awọn aṣẹ ti e gba lodo awon oluko igbala yin. Ka to forogun, tani oluko igbala yin?
Prabhupada: Oruko Oluko mi ni Om Visnupada Paramahamsa Bhaktisiddhanta Sarasvati Gosvami Prabhupada
Oniifọrọwanilẹnuwo: Bayi ninu iran ti at'owo d'owo ti a nsoro nipa re seyin, iran at'owo d'owo awon iranse yi lọ pada sẹhin, lọ sẹhin sẹhin titi kan Olorun fúnra Rẹ, abi, se oluko igbala yin ni asaaju tele ki o to kan yin?
Prabhupada: Beeni. Iran at'owo d'owo awon iranse ti odo Olorun wa niwon egberun marun odun seyin.
Oniifọrọwanilẹnuwo: Se oluko igbala yin si wa laaye?
Prabhupada: Rárá. O ti kọja lọ ni 1936.
Oniifọrọwanilẹnuwo: Be ni eyin ni e wa je olori agbaye ni akoko pato yi fun egbe yi? Se beko?
Prabhupada: Mo si ni awon ọpọlọpọ egbe arakurin miiran, sugbon won pa laṣẹ fun mi ni paapa lati se eyi gan ni ibẹrẹ. Be ni mo ngbiyanju lati se itelorun oluko igbala mi. Ko ju yen lo.
Oniifọrọwanilẹnuwo: Bayi won ti ran yin wa si orile-ede yi, America. Eyi ni agbegbe yin. Se beko?
Prabhupada: Agbegbe mi, ohun ti won so ni wipe: Lo se iwaasu imo yi fun awon elede Geesi".
Oniifọrọwanilẹnuwo: Fun awon elede Geesi.
Prabhupada: Bẹẹni. Ati paapa ni iwo-oorun aye. Bẹẹni. Bi o se so fun mi gee ni yen.
Oniifọrọwanilẹnuwo: Nigbati e si de, alaagba, si orile-ede yi boya bi odun karun-dinlogun,tabi kerin-dinlogun seyin, e si bere...
Prabhupada: Rara, rara, kii se odun 15 tabi 16.
Oniifọrọwanilẹnuwo: Odun marun, si mefa, ema binnu. Ni agbegbe aye ti e wa yi, kii se agbegbe aye nibi ti esin se be s'owon, se e mo. Ni orile-ede Amerika a ni ọpọlọpọ awọn esin, mo si lero pe awon eniyan ni orilẹ-ede yi fẹ lati gbagbọ, opolopo ninu won, pe won je eniyan rere, awon eniyan ti won gba Olorun gbo, ti won fi t'okan t'ara wọn sinu orisi esin sise. Mo si ṣe kàyéfì ohun ti ero yin jẹ. Kini ohun ti eyin rope e le fi kun awon ise-esin ti won ti wa nle tele ni orile-ede yi nipa wiwa yin ati fi-fikun imo ti yin pelu re?
Prabhupada: Beeni. Nigbati mo koko de orile-ede yin, mo je alejo l'odo ore ara ilu India ni Butler.
Oniifọrọwanilẹnuwo: Ni Pennsylvania.
Prabhupada: Pennsylvania. Beeni Biotilejepe o je ilu kekere kan, sugbon inu mi si dunsi gidi gan pe ọpọlọpọ awon ile-ijosin ni won wa nibẹ.
Oniifọrọwanilẹnuwo: Opọlọpọ awon ile-ijosin. Beeni. Beeni.
Prabhupada: Beeni. Opọlọpọ awon Ile-ijosin. Mo si se waasu ni opolopo awon ile-ijosin nibe. Agbalejo mi lo seto gbogbo eleyi. Kii se fun idi eyi, ni mo se wa sibi lati ṣẹgun awon ilana esin . kan. Iyen kii se ipinnu mi. Ise wa ni, ise Oluwa Caitanya ni, lati kọ gbogbo eniyan bi o ṣe le ni ife Ọlọrun, ko ju yen lo..
Oniifọrọwanilẹnuwo: Sugbon ni ona wo, Alagba, bi e ba se mi ni gafara ki nbere, ni ona wo ni e ro pe, ati bawo ni e se le ro nisinyi, wipe awọn ẹkọ ifẹ ti Ọlọrun ti eyin nse, o yatọ si ati boya o dara ju awọn ẹkọ ifẹ ti Ọlọrun ti won ti nse tẹlẹ ni orilẹ-ede yi ti won si ti nse niiha iwo oorun fun orundun?
Prabhupada: Otito oro niyen. Nitoripe awa ntele ipasẹ Oluwa Caitanya A kà kun... A gbà fun wa - ni ibamu aṣẹ ti awon iwe Vediki - Oun fun Ra re ni Olorun.
Oniifọrọwanilẹnuwo: Oluwa wo niyen?
Prabhupada: Oluwa Caitanya.
Oniifọrọwanilẹnuwo: Iyen beeni. Oun lo pada wa ni ẹdẹgbẹta odun seyin si India?.
Prabhupada: Bẹẹni. Nítorí náà, ó jẹ Olorun fúnra Rẹ, O si wa nkọ bi a se le ni ife Olorun. Nitorina ilana Re ti wa ni aṣẹ julọ. Gege bi eyin se je amoran ninu ile -ise yi. Ti ẹnikan ba nṣe nkan, ti o ba kọ funrara rẹ, "Se ba yi," iyen je ohun ti o wa ni aṣẹ gidigidi gan. Bee na isokan Olorun, Olorun, fúnra Rẹ kọni. Gege bi ninu iwe mimo Bhagavad-gita, Krishna ni Olorun. O si wa nsoro nipa ara rẹ. Ati ni kẹhin O si wipe, "Ki o kan jowo ara re fun mi." Emi o se itoju re." Sugbon ko ye awon eniyan. Nítorí náà Oluwa Caitanya - Olorun tún wá, bi Oluwa Caitanya, lati kọ eniyan bi o ṣe le jowo. Ati nitori pe a ntẹlé awọn ipasẹ ti Oluwa Caitanya, awọn ọna ti o jẹ gíga bẹẹ ti awon àjeji paapaa ti won ko mo nipa Krishna gan, awon na si njowo emi won. Itosona yi l'agbara gan. Bee ni eyi je ilepa mi. Awa o nso wipe "Esin yi dara ju esin yi lo", tabi " Ilana temi lo dara ju." A fe ri nipa awon abajade. Ninu ede Sanskrit oro kan wa, phalena pariciyate. Nipa abajade ohun kan ni a fi ndajo.
Oniifọrọwanilẹnuwo: Nipa kini ohun kan nse ni idajo...?
Prabhupada: Nipa awon àbáyọrí.
Oniifọrọwanilẹnuwo: Bee lo je.
Prabhupada: O le sọ, mo le sọ pe ọna mi ni o dara gidigidi. O le so pe ọna rẹ ni o dara gidigidi, sugbon a ni lati ṣe idajọ nipa awọn àbáyọrí. Ìyẹn ni pé ... Bhagavata sọ wipe ilana esin ti o dara gidigidi ni eyi ti, nipa titele, a le di ololufe Olorun.