YO/Prabhupada 0140 - Ele huwa to da, tabi ke huwa tioda
Lecture on SB 6.1.45 -- Laguna Beach, July 26, 1975
Ninu egbe imoye Kṛṣṇa yi, afe fiye awon eyan pe otipe tonti jiya. Nisin awon eyan otie mowipe aye atunwa n'be. Wanti ni ilosiwaju gan. gege bi awon aja at'ologbo, awanna otie mo boya aye mi si wa lehin eleyi. wansi sowipe: yena yāvān yathādharmo dharmo veha samīhitaḥ. Iha, itumo iha i " ninu aye yi". Sa eva tat-phalaṁ bhuṅkte tathā tāvat amutra vai. Itumo Amutra ni " ile-aye to kan". Awasin s'eto ile-aye wa tokan ninu... Yatha adharmaḥ, yathā dharmaḥ. Nkan meji lowa: ele huwa to da, tabi ke huwa tioda. Kos'ona iketa. Ona kan da; ikeji oda. wansi ti soro nipa awon mejeeji. Yena yāvān yathādharmaḥ, dharmaḥ. t'olofin ni itumo Dharma. Oni iwe itumọ-ọrọ kan to sowipe " iru esin kan" ni itumo Dharma. Iro niyen. Awon Esin afoju lewa. Dharma koniyen. Ojulowo ni itumo Dharma. Dharma niyen, moti sobe aimoye igba.. Gege bi omi, Ololomi ni omi. dharma niyen. ti omi badi yinyin, sugbon osile pada s'omi nitoripe dharma re niyen. teba sifi yinyin na sile, asi d'omi pada. Itumo yen niwipe omi to lee, omi eke niyen. pelu ise awon kemika omi na ti lee, sugbon ololomi ni iwa aseda re.
Gege bi Ipo wa seri niyen: "Awa o fe gbo nkankan nipa Olorun." Sugbon iwa aseda tani niwipe iranse Olorun niwa Nitoripe afeni Oga.. Krsna ni Oga to gaju. Bhoktāraṁ yajña-tapasāṁ sarva-loka maheśvaram (BG 5.29). Krsna sowipe, " Emi l'oga gbogbo agbaye. Onigbadun nimi." Oga loje. . Caitanya-caritāmṛta sowipe ekala īśvara kṛṣṇa. Olori ni itumo Īśvara. Ekala īśvara kṛṣṇa āra saba bhṛtya: "Iranse nigbogbo awon eda aye yi afi Kṛṣṇa." Eyin na leri wipe Kṛṣṇa o sise fun enikankan. Bhoktāraṁ yajña-tapasāṁ sarva-loka... Awon eyan bi awa, agbudo sise na katole gbadun. Krsna o ni lati sise.Na tasya kāryaṁ kāranaṁ ca vidyate. sugbon osin gbadun. Krsna niyen. Na tasya... Iroyin Veda niyen Na tasya kāryaṁ kāranaṁ ca vidyate: Olorun, Krsna, konise kankan lati se." Nitorina ema ripe gbogbo igba ni Krsna ati gopi n'jo, tabi koma sere pelu awon omo-okurin oluso-maalu. Toba deti re, asi sun legbe eti-odo Yamuna, lesekese niawon ore re mawa ba. Awon mi ma fe lategun, awonmi ma fi ọwọ wọ ara fun Nitorina Oga loje, ibikibi toba lo, Oga loje. Ekala īśvara kṛṣṇa. Īśvaraḥ paramaḥ kṛṣṇaḥ (Bs. 5.1). Krsna ni Oludari. Tani Oludari? Koseni tole p'ase fun. Krsna niyen. Nibi aledi Olori fun nkan bayi bayi, tabi Olori Ilu America, sugbon miole di Olori togaju. lesekese ti awon bafe wanle fa eyan sile kosi yewa pe awa fed'oga, Sugbon elomi lon p'ase funmi. Olori ko loje. Ni ile aye yi, awon Olori wa, sugbon awon na gbudo daaun si Olori to gaju wan lo. Sugbon Krsna ni olori to gaju. Krsna niyen, Olorun niyen. Sayensi imoye niyen. Itumo Olorun niwipe oun ni oludari gbogbo nkan, koseni tole p'ase fun.