YO/Prabhupada 0181 - Mole ni ibasepo tinmotinmo pelu Olorun
Evening Darsana -- August 9, 1976, Tehran
Prabhupada: Itumo Ikeko ninu eto mimo niwipe ni alakoko agbudo n'ìgbàgbọ pe " mole ni ibasepo tinmotinmo pelu Olorun." Afi teyin ba ni iru ìgbàgbọ bayi, kosejo pe e fe gba ikeko ninu eto mimo. Teyin ba kon sowipe , " Alagbara ni Olorun je, eje ko wa ni ile re, emi na joko si ile mi, " Ife koni ye je. Egbudo gbiyanju lati mo nipa Olorun tinmotinmo. Ese to kan niwiwpe bawo lesefe mo nipa Olorun afi teba sunmo awon onise Olorun ton sise fun. Awon eyan yi o ni ise imi. gege bi awa sen fun awn eyan l'eko, fun ise Olorun nikan. Awon eyan yi o ni'se imi. Bawo niawon eyan yi sefe mo nipa Olorun, bawo ni wan sefe jeere, wan se orisirisi eto. Agbudo ni asepo pelu awon eyan ton niìgbàgbọ nipa Olorun ton sise lati pin oro re kaakiri agbaye. Agbudo rin pelu awon eyan bayi. Ni alakoko egbudo mowipe, " Ni aye yimo wa yi mo gbudo ni oue nipa eto Olorun." Lehin na ele ni asepo pelu awon eyan ton sise Olorun. Lehin ele sise bon se sise. Lehin na gbogbo iyemeji teni ma tan. Lehin na ema ni ifarafun. Lehin na ema ni itowo fun. gege bayi ele ni'fe fun Olorun.
Ali: Moti niìgbàgbọ yi .
Prabhupada: Egbudo sise ko posi. ìgbàgbọ t'alakoko da gan sugbon afi teyin ba sise lati jeko posi, kole si ilosiwaju nibe.
Parivrājakācārya: Se igbagbo yi le sonu.
Prabhupada: Beeni, teyin o ba gbiyanju lati ni ilosiwaju, nigbana lema ni isoro pelu igbagbo teba ni, nitoripe o ma tan.