YO/Prabhupada 0389 - The Purport to Hari Hari Biphale
Purport to Hari Hari Biphale -- Hamburg, September 10, 1969
Hari hari! biphale janama goṅāinu. Orin Narottama dāsa Ṭhākura leleyi, acarya to daju, tosije ikan ninu awon akeko lati Caitanya Mahāprabhu's sampradāya, O ti ko orin to po gan, awon orin re si dabi ofin niu awon Veda. Awon orin ton dabi ofin. Beena on gbadura s'Olorun Krsna, " Olorun mi," hari hari, " Moti b'aye mi je." Hari hari biphale janama goṅāinu. Kilode tose ba aye re je? O sowipe, manuṣya-janama pāiyā, " Moti gba ara eda yi," rādhā-kṛṣṇa nā bhajiyā, "sugbon mio gbiyanju lati s'adura si Radha-Krsna. Nitorina moti ba ie aye mi je." Bawo lose je? Gege b'eyan to mo koto mu majele. Teyan o ba mo koto mu majele, nkan imi niyen, sugbon toba mo tosi mu majele, ipara eni loje. O sowipe " bi ipara eni loje nitoripe mio s'adura si Rādhā ati Kṛṣṇa ninu ara eda yi."
Lehin na o sowipe, golokera prema-dhana, hari-nāma-saṅkīrtana. Egbe imoye Krsna yi, egbe saṅkīrtana yi, nkaj aye yi ko loje. lati odo metalokan ton pe ni Goloka Vrndavana loti wa. Beena golokera prema-dhana. Orin lasan ko loje. Isura ife lat'odo metalokan. Beena.. " Sugbon mio ni ifarafun." Rati nā janmilo kene tāy. "Mio ni ifarafun. Lodi keji, " viṣaya-biṣānale, dibā-niśi hiyā jwale, "sugbon nitoripe mio gba, ina mejele yi tin jomi." Dibā-niśi hiyā jwale. "Lat'aro d'aale, okan mi n'jona nitori majele ile aye yi." taribare nā koinu upāy."Sugbon mio wa ona abayo kankan fun." Ni gbolohn miran, egbe sankirtana y ni ona abayo fun ina ton jo yi. Lati odo metalokan loti wa. talo muwa? Talo gbe wa?
Lehin na o sowipe, brajendra-nandana jei, śaci-suta hoilo sei. Brajendra-nandana, Omo-Oba Braja. Krsna niyen. Oruko imi fun Krsna ni omo Nanda Maharaja. Oun l'Oba Brajabhumi. brajendra-nandana jei, eyan kanna toje omo Nanda-Maharaja, ti farahan nisin bi omo-okurin Iya Śacī. Śacī-suta hoilo sei. balarāma hoilo nitāi. Oluwa Balarāma tidi Nityānanda. Awon aburo mejeji wanyi ti farahan, lati fun awon eda elese aye yi nigbala. Pāpī-tāpī jata chilo. Gbogbo awon eda elese ninu agbaye yi, ni won fun nigbala pelu ilana orin kiko yi. Hari-nāme uddhārilo, lati orin kiko yi. Bawo lon sele se? Lehin na o sowipe, tāra sākṣī jagāi and mādhāi. Apeere to wa ni awon aburo meji, Jagāi ati Mādhāi. Awon aburo mejeji , Jagāi ati Mādhāi, inu ebi brahmana lon bi won si, sugbon wan si di odaran . A mowipe, lasiko tawayi, iru iwa ton ni o kin se ikan to buru. Iwa won tio da niwipe won feran oti mimu at'obirin. Nitorina lon sen pe won ni awon onisekuse. Ati awon ton jeran na. Sugbon lehin na wansi ni igbala lati ore-ofe Oluwa Caitanya ati Nityananda. Awon olufokansi pataki.
Beena Narottama dāsa Ṭhākura ti salaaye wipe ninu asiko tawayi, botilejepe awon eyan feran oti mimu, obirin, eran jije, kon ma ta tete, ati awon iwa ese orisirisi, sugbon, tonba si gba egbe imoye Krsna yi ton korin Hare Krsna, wan ma ni ominiran. Ibukun Oluwa Caitanaya niyen. Lehin na Narottama dāsa Ṭhākura gbadura, hā hā prabhu nanda-suta, vṛṣabhānu-sutā-juta. " Oluwa mi Krsna, Eyin l'omo Oba Nanda, Rādhārāṇī toje aya re,ni omo-obirin Oba Vṛṣabhānu. Eyin mejeji lesi duro sibi." Narottama dāsa kahe, nā ṭheliho rāṅgā pāy, "Nisin moti teriba fun yin, Ema timi segbe kan pelu ese yin to dabi ododo, nitoripe mio ni idaabo imi. Moti gba idaabo ese yin lai ni nkan imi. Beena edakun egbami kesi funmi nigbala." Koko oro orin yi leleyi.