YO/Prabhupada 0497 - Everyone is Trying not to Die
Lecture on BG 2.15 -- Hyderabad, November 21, 1972
Ninu ile aye yi, awa ninu mrtatva, agbdo se ibimo, iku, d'arugbo ati aisan. Sugbon ipo imi wa nibi toje pe kosi'bimo, kosi'ku, eyin o ni darugbo kode s'aisan. Beena ipo wo lawa fe - ibimo, iku, ojo-arugbo at'aisan, tabi ibi tio sibimo, tio si'ku, eyin o ni darugbo, kode s'aisan? Ewo lefe? Hmm? Mo rowipe o daju tabafe ibi tio si'bimo, tabi iku, tabi ojo arugbo, tab'aisan. Beena nkan tonpe ni amrtatva niyen. Beena amṛtatvāya kalpate. Amrta...Base wa lori ipo wa t'alakoko, awa o ni ibimo, iku, darugbo tabi ka ni aisan. gege bi Kṛṣṇa se je sac-cid-ānanda-vigraha (Bs. 5.1), tayeraye, idunnu, imoye to peju, beena awa na, nitoripe nkankana laje pelu Krsna, amuye kanna lani. Ati gba ipo ibimo, iku, ojo arugbo anti aisan yi, Nitori asepo tani pelu ile aye yi. Nisin, koseni tofe ku, awon eyan osi fe darugbo, gbogbo awon eyan lon sa fun iku. Nkan adanida loje. Nitoripe, ni alakoko, awa o si labe awon nkan wanyi, Nitorina ise ni wipe agbodo sise gan, lati mo basele koja ipo iku, ibimo, aisan. Itiraka to wa niyen latigbe ninu aye yi.
Beena nibi, ninu Bhagavad-gita, wanti salaaye nipa awon fomula to da. Yaṁ hi na vyathayanty ete puruṣaṁ puruṣarṣabha. iyipo ti emi wa lat'ara kan sikeji, enikeni ti awon nkan wanyi o joo loju, dhīras tatra na muhyati (BG 2.13), eni toba ni oye na.... Kasowipe baba mi ti ku, tobe ye mi wipe " baba mi ko loku. O kan paaro ara re. Oti gba ara imi." Otooro leleyi. Gege bi t'aba n'sun, tan laala, ara mi si wa lori ibusun, sugbon ninu ala mi mo ni ara imi toyato nibi to jina gan sibi timo wa. Beyin seni ijeeresi lojojumo, beena, ara eda lasan yi le paari, sugbon Emi, emi mimo, mio le paari. Mon sise. Okan mi sinn rin kaakiri. Okan mi n'sise ni gbogbo'gba, ogbon mi sin sise. Awon eyan o mope ara imi wa t'awa o le foju ri tojepe lati okan wa, ogbon wa ati igberaga wa loti wa. Eleyi ma gbemi losi ara eda imi tale foju ri. Nkan ton pe ni iyika emi lat'ara kan sikeji. Nitorina eni toba mope emiwa wa tayeraye, kole ku, kole nibimo, osi wa tuntun nigbogbo'gba, nityaḥ śāśvato 'yaṁ purāṇaḥ. Nityaḥ śāśvataḥ ayaṁ purāṇaḥ. Nkan toti darugbo nitumo Purāṇa. Awa o mo iye ojo ori wa, nitoripe awa sin paaro ara kan fun imi. Awa o mo nigbata bere gbogbo eleyi. Nitorina, niotooro awa ti darugbo gan, sugbon nigbakana, nityaḥ śāśvato 'yaṁ purāṇaḥ. Botilejepe nkan toti darugbo gan... Beena ādi-puruṣa ni Krsna je, eda t'alakoko. Beena, eyin na ma ri Krsna bi okurin, pel'ojo ori merindinlogun si ogun. Eyin o le ri iworan Krsna nibi to dabi arugbo. Nava-yauvana. nava-yauvana ni Krsna je nigbogbo'gba. Advaitam acyutam anādim ananta-rūpam ādyaṁ purāṇa-puruṣaṁ nava-yauvanam (Bs. 5.33). Ādyam, eda t'alakoko, to darugbo ju, nigbakana, osi wa lasiko ewe re. Ādyaṁ purāṇa-puruṣaṁ nava-yauvanam. Beena enikeni toba mo, bi emi sen paaro ara kan sikeji, dhīras tatra na muhyati, awon eyan ton wa jeje, to logbon, kosi nkankan tole fun ni idamu.
Krsna fe ko Arjuna ni awon nkan wanyi... nitoripe o ni idamu to po lati mo bosele gbe, base pa awon ebi re, awon omo-okurin aburo re. Beena si fe salaaye fun wipe " Awon aburo at'egbon okurin re, ati baba'gba re kosi bonsele ku. Won ma paaro ara kan fun ikeji. Vāsāṁsi jīrṇāni yathā vihāya (BG 2.22). Basen paaro aso wa beena lasen paara ara eda eyan yi. Kosidi fun ekun sisun." Nibomi, Bhagavad-gita, nitorina, wansi sowipe, brahma-bhūta (BG 18.54). " Eyan gbodo ni oye nipa Brahman," prasannātmā, "inu re dun nigbogbo'gba. Awon nkan aye yi o le fun ni idamu." Won ti salaaye nibi: yaṁ hi na vyathayanty ete. Awon ìyípòpadà wanyi, awon iyika orisirisi t'iseda, ara ati gbogbo nkan, eyan o gbodo jeki awon nkan wanyi fun ni idamu. Awon nkan ti'ta leleyi. Emi mimo niwa. ara lasan, tabi aso re tita loje. Nkan ton paaro niyen. Beena toba ye wa dada, na vyathayanti, teyin o ba jeki awon nkan wanyi funyin ni idamu, lehin na saḥ amṛtatvāya kalpate, lehin na oti ni ilosiwaju niyen, ilosiwaju mimo. Itumo re niwipe, itumo ilosiwaju mimo yi niwipe, osin tesiwaju si aye tayeraye. tayeraye nitumo ile aye mimo, aye idunnu to pe pelu imoye. Ile aye mimo niyen.