YO/Prabhupada 0563 - Give the Dog a Bad Name and Hang it



Press Interview -- December 30, 1968, Los Angeles

Akoroyin: eje kin biyin leere.. Moni nkan timo ro, sugbon mofe biyin. Kilode teyin ro rope nidi toje awon eyan lasiko ewe won leni won koju si awon esin lati awon ilu ni asia?

Prabhupada: Nitoripe eyin o le fun won nitelorun.

Akoroyin: Kile so?

Prabhupada: Nitoripe eyin o le funwon nitelorun. Ile aye lasan teyin gbe kole funwon nitelorun mo. Ipo kan wa, ni alakoko, teyan o ba baje talaka, O le rowipe " Owo ati obirin ati ile to da, ati moto to da le funmi ni itelorun." Nkan ton wa niyen. Sugbon lehin igba ton ba gbadun re tan, won ma ri wipe " Oh, kosi itelorun kankan." Nitoripe oun aye yi o le fun yin nitelorun. Beena ipo yin ninu orile-ede America niwipe eyin tini igbadun to po. Eyin l'ounje to po, eyin ni obirin to po, eyn ni oti to po, eyin ni ile to po - gbogbo nkan lo to. Eleyi fi hon pe ilosiwaju ninu eto ile aye yi kole funwa nitelorun kankan. Idamu ati ainitelorun yi po gan ninu orile-ede yin ju India lo, toje pe awon eyan je talaka. Se ri bayi? Sugbon eyin ma riwipe nin India botilejepe talaka ni awon eyan, nitoripe won tele asa won, kosi idamu kankan. Beeni> Won ku die die sugbon o te won lorun pe. " O da bee." Seri bayi? Kilode? Nitoripe won ni ifarafun nkan mimo. Beena nkan pataki loje fun awon eyan lati gba ile aye mimo yi. O ma je ki inu won dun si. Ireti wa. gbogbo awon eyan yi wa ninu okunkun. Won o mo ibi ton lo. Kosi àfojúsùn kankan. sugbon teyin ba wa lori ipo mimo, eyin ma mo nkan teyin se, ibi teyin lo, nkan ti ojowaju yin je. Gbogbo nkan lo daju. Seri bayi?

Akoroyin: Beena nisin loye mi nkan teyin so. Beena nkan teyin so niwipe ile-ajosi ilu geesi, boya ile adura tabi ile Olorun, won ti kuna ninu eto .. Seyin ma sowipe oro ton fun awon nio daju tabi won o mo bonsele fun awon eyan l'oro Oluwa dada?

Prabhupada: Rara. Nkan towa ni awon ile-ajosin yi ni ilu geesi , niwipe gege bi esin onigbagbo, iwe bibeli yi oti pe ton ti soro na, se ri bayi? Jerusalem. Awon eyan wanyi wa ninu ile gbigbe, kode si ilosiwaju to po nigbana. Looto, ninu Bibeli tabi ninu apa atijo, eri nipa Oluwa wa nibe, iyen na da gan. Sugbon bi oro yi pe, "Oluwa da aye yi." Oto oro niyen. Nisin awon eyan tio ni ilosiwaju... Nisin, lasiko tawayi awon eyan ni ilosiwaju ninu eto sayensi. Won fe mo bonse da àgbáyé yi. Se ri bayi? Awon àlàyé yi o si nibe, ile ajosin gan o le funwon. Se ri nisin. Nitorina kosi itelorun. Pe won losi ile-adura lati gbadura nikan, iyen o to fun won. Afi eleyi nikan, awon eyan yi o tele awon ofin esin kankan. Gege bi apa atijo, awon ofin mewa wa nibe, ofin kan si sowipe " Ema fiku pa." Sugbon awon eyan sin se ninu esin onigbagbo. won ni awon ile-iperan, wonde ti sowipe awon erank o l'eemi kankan, kos'aye ninu won - nitoripe wonfe pa won. " Efun aja yi ni oruko tio da ke pa." Kilode ti awon eranko o l'eemi? Kilode teyin sen huwa elese wanyi? Beena awon alufaa gan o ni soro, koseni ton soro. Beena awon eyan sin ṣàìgbọràn si awon ofin mewa. Beena nibo ni ofin esin na wa? teyin o ba le tele awon ofin ninu iwe mimo teni se iyen fihon pe eyin tele esin yin dada? Kilode teyin sen pa nkan teyin o le das'aye? Won de ti so nibe, " E ma fiku pa." Kini idaaun na? Kilode tonse fiku pa? Kini idaaun na? Bawo lese fe daaun si?

Akoroyin: Sen bimi?

Prabhupada: Beeni.

Akoroyin: Beeni, o daju pe " Ema fiku pa" ofin yi wa nibe, lataye atijo osi daju, sugbon awon okurin o foju si ....

Prabhupada: Awon eyan o fuju esin. won kan se bose wuwon. Lehin na bawo ni inu won sefe dun? Teyin o ba tele awon ofin wanyi, nibo ni esin yin wa?

Akoroyin: Mio ba yin jiyan. Kosi bi mio sele gba. Mogba gbogbo nkan teyin so. Kode s'ogbon kankan. " E ma fiku pa," " Ema sin Oluwa imi ju Emi lo." " Ema mu ohun elo ti aládùúgbò yin," " E gboran si baba ati iya yin," awon ofin yi lewa gan sugbon koseni ton tele.

Prabhupada: " Ema mu iyawo aládùúgbò yin."

Akoroyin: Iyawo, jigbe.

Prabhupada: Beena talon tele awon ofin wanyi?

Akoroyin: Koseni kankan. iwonba die.

Prabhupada: Seri bayi? bawo leyin serope awon eyan yi fe di onigbagbo, lai si esin awujo eyan dabi awon eranko.

Akoroyin: O da, sugbon eje kin bere Nisin mio bere...

Prabhupada: gba. gba.

Akoroyin: Ese pupo.