YO/Prabhupada 1060 - Afi teyan ba gba Bhagavad-gita pel'emi to resile...



660219-20 - Lecture BG Introduction - New York

Sarvam etad ṛtaṁ manye (BG 10.14). " Mo gba bee, ounkoun teba so, moti gba bi ooto. Osi le gan lati ni oye nipa Olorun. nitorina awon orisa gan o le mo nipa re. Awon orisa gan o le mo nipa yin." Itumo re niwipe awon eda ton gaju awon eda eyan lo, o si le gan fun won lati mo nipa eni t'Olorun je, bawo ni awon eda eyan se fe mo nipa Sri Krsna lai di olufokansi fun?

Nitorina oye ka gba Bhagavad-gita pelu emi awon olufokansi Oluwa Sri Krsna. Eyan o gbodo rowipe oti wa lori ipo kana pelu Sri Krsna, tabi keyan rowipe eyan lasan loje, tabi eyan pataki. Non. Eledumare ni Oluwa Sri Krsna je. Beena lori oro yi ninu Bhagavad-gita tabi lori oro Arjuna, Eni toba fe ni oye nipa Bhagavad-gita, oye ka gba wipe Eledumare ni Sri Krsna je, beena pelu emi to resile yi... Afi teyan ba gba Bhagavad-gita pelu emi to resile ati igboran to daju, O si le gan lati ni oye nipa Bhagavad-gita nitoripe iyanu nla loje.

Beena ninu Bhagavad-gita yi... A le wo nkan ti Bhagavad-gita je. Lati yo awon eyan kuro ninu okunkun ile aye yi ni Bhagavad-gita yi wa fun. Gbogbo eda loni isoro kan tabi keji, bi Arjuna se wa ninu isoro lori eto ogun Kuruksetra. beena osi teriba fun Sri Krsna, nitorina lonse so Bhagavad-gita yi. Beena, Arjuna ni kan ko sugbon gbogbo wa lani isoro nitori ile aye yi. Asad-grahāt. Igbese aye wa inu ile aye yi tabi lori ofurufu lowa. Sugbon looto oro, awa o kinse alaisi laye. Igbese aye wa tayeraye lowa fun, sugbon bakana awa ti wa ninu asat yi. Nkan tio si laye nitumo Asat.

Nisin ninu gbogbo awon eda ton sewaadi lori ipo aye won lati mo eni ton je, kilode to sen jiya.. Afi teyan ba jisoke lati ipo yi pe, kilode ti mo sen jiya? Mio fe iru awon ijiya bayi. moti gbiyanju lati sewaadi fun ona abayo fun gbogbo ijiya wanyi, sugbon moni aseyori." Afi teyan ba wa lori ipo bayi kosi bose le je eda pipe. Igbese aye eda bere leyin igba toba sewaadi lori awon eto wanyi l'okan re. Ninu Brahma-sutra brahma-jijñāsā lonpe iwaadi yi. Athāto brahma jijñāsā. Ikunna ni gbogbo ise eda eyan tio ba ni ibeere yi lokan. Beena awon eyan ton ti ji ibeere yi soke lokan won pe " kilode ti mosen jiya, nibo ni moti wa tabi nibo ni maa lo leyin iku," lehin igbati awon ibeere wanyi ba ji soke ninu okan eda eyan to logbon, lehin na lole di oluko gidi fun imoye Bhagavad-gita. o gbodo di śraddhāvān. Śraddhāvān. O gbodo bowo, ibowo fun Eledumare. Iru eyan bayi, Arjuna ni iru eyan bayi.