YO/Prabhupada 1064 - Oluwa si wa ninu okan gbogbo awon eda



660219-20 - Lecture BG Introduction - New York

Oluwa wa ninu ọkan gbogbo ẹda alãye kọọkan, Imoye ti o gaju, yio ni alaye ninu Bhagavad Gita. ninu ori iwe ti iyatọ to wa laarin jiva ati īśvara yio ni alaye. Kṣetra-kṣetra-jña. Wanti salaaye nipa kṣetra-jña yi, Oluwa ni kṣetra-jña, ati awon jiva, tabi awon ẹda alãye, awon na nimọ ninu. Sugbon iyato to wa niwipe awọn ẹda alãye nimọ pato ti ara rẹ sugbọn Oluwa nimọ ti gbogbo ara. Īśvaraḥ sarva-bhūtānāṁ hṛd-deśe 'rjuna tiṣṭhati (BG 18.61).

Oluwa wa ninu ọkan gbogbo ẹda alãye kọọkan, O nimọ awọn ero inu irinkerindo ti awọn jīvas ni pato. Ko yẹ ki a gbagbe eleyi. O tun ti wa ni alaye pe Paramātmā, Ọlọrun Eledumare, ngbe ninu ọkàn gbogbo eniyan bi īśvara, bi oludari, o si nfun ẹda alãye ni itọsọna. O nse itosona. Sarvasya cāhaṁ hṛdi sanniviṣṭhaḥ (BG 15.15). O ngbe ninu ọkàn gbogbo eniyan, o si nfun ẹda alãye ni itọsọna lati se bi o ti wu. Ẹda alãye gbàgbé ohun to ni lati ṣe. akọkọ yio se ipinnu lati sisẹ ni ọna kan, lẹhinna a bọ sinu idimu karma awọn isẹ ọwọ rẹ ati ere wọn. Lẹhin ti iku ba ti pa l’ara da, a gbe ara miiran wọ... gẹgẹ bi a se nparọ aṣọ kan fun imiran, bakanna, o ti wa ni alaaye ninu Bhagavd-gita pe vāsāṁsi jīrṇāni yathā vihāya (BG 2.22). Gege bi eyan se nwo ewu orisirisi, beena ni awon eda se nyi ara pada ni orisirisi, Bi ẹmi ba se kuro bayi lati ara kan si ara miran, a jẹ iya awọn ise ọwọ rẹ ati ere wọn ti o ti rekọja. Awọn akitiyan wọnyi le se yipada nigbati ẹda alãye ba wa ninu ipo rere, ni ilera ọkan, ti o si mọ iru akitiyan ti o yẹ ki o gbọwọle. Ti o ba se bẹ, gbogbo awọn ise ọwọ rẹ ati ere wọn ti o ti rekọja le ni ayipada. Nitori naa, karma ki ise fun ayeraye. wipe ninu awọn ohun marun yi -- īśvara, jiva, prakriti, kala ati karma -- mẹrin ni wọn jẹ ainipẹkun, sugbọn karma ki ise fun ayeraye.

Onimọ to ga julọ īśvara, ati iyato laarin isvara to gaju ju tabi Oluwa, ati awon eda ninu asiko tawayi, o ri bayi. imoye ti Ọlọrun ati ti ẹda alãye ni wọn jẹ imọlẹ Ki ise wipe imoye bẹrẹ si ndagba labẹ awọn ayidayida apapọ awọn ohun elo aye. Asise ni eyinni jẹ. Ero ori ti o wipe imoye bẹrẹ si ndagba labẹ awọn ayidayida apapọ awọn ohun elo aye ko ni asẹ ninu Bhagavad Gita. Ko le jẹ bẹ Imoye ti le tan mọlẹ sodi nipa ibora ti awọn ohun elo ọran aye, gẹgẹ bi ina ti o tan mọlẹ nipasẹ dingi gẹgẹ bi ina ti o tan mọlẹ nipasẹ dingi alawọ le fihan gẹgẹ bi awọ kan. Beena, imoye Oluwa, ko ni nkankan se pelu ile aye yi. Oluwa, gege bi Krsna, O sowipe, mayādhyakṣeṇa prakṛtiḥ (BG 9.10). Nigbati o sọkale sori-lẹ agbaye, ohun elo aye ko ni ipa lori imoye Rẹ. Ti o ba ti ni ipa lori Rẹ, o ma wa laitọ fun lati sọrọ lori ọrọ imọlẹ bi o ti se ninu Bhagavad Gita Eniyan ko le sọ ohunkohun nipa ti aye imọlẹ lai ni ominira kuro ninu abawọn ọkan aye. Bẹẹ ni abawọn aye ko ni ipa lori Oluwa. Sugbon imoye aye wa lasiko yi, si ni doti aye yi. Iwe mimọ Bhagavad Gita fi kọni pé a ni lati ya imoye ti o ti ni abawọn aye yi si mimọ, Ninu imoye mimọ, awọn ise wa yoo wa ni ibaamu si ifẹ ti īśvara eyi yoo ṣi fun wa ni idunnu. Ki ise pe a ni lati siwọ ninu gbogbo awọn akitiyan. Awọn akitiyan wa ni lati ni ya si mimọ. awọn akitiyan alailabawọn ni a npe ni bhakti. Awọn akitiyan ninu bhakti le dabi awọn akitiyan ti ki ise pataki, sugbọn wọn ko ni abawọn. Ise mimọ lo je. Alaimọkan eniyan le ri pe olufọkansin nhuwa tabi nsisẹ bi eniyan yẹpẹrẹ, sugbọn iru alaimoye eniyan bẹ, se aimọ wipe awọn akitiyan ti ẹlẹsin tabi isé Oluwa, ko nni ibajẹ nipa imoye eleeri tabi abawọn aye, Wọn ni imọlẹ lori awọn ipo mẹta ti isẹda. o yẹ ki a mọ pe akoko ti a wa yi imoye wa ti ni abawọn.