YO/Prabhupada 1067 - Agbodo gba oro iwe Bhagavad-gita lai se isotunmo si, lai yo oro kankan kuro

From Vanipedia
Jump to: navigation, search
Go-previous.png Previous Page - Video 1066
Next Page - Video 1068 Go-next.png

Agbodo gba oro iwe Bhagavad-gita lai se isotunmo si, lai yo oro kankan kuro - Prabhupāda 1067


660219-20 - Lecture BG Introduction - New York

A gbọdọ gba Bhagavad Gita lai fun ni itumọ, laisi piparẹ Iranwọ pipe ti wa nibẹ fun awọn pipe kekere kọọkan, eyunni awọn ẹda alãye, lati mọ ọran pipe. ati gbogbo iruru alaipe ti wa ni ìrírí nitori idabọ imọ àsepe.

Bẹ ninu Bhagavad Gita ni awọn imọ pipe ti ọgbọn Vediki wa. Gbogbo imọ ilana Vediki jẹ Ọrọ Ọlọrun. Orisirisi awọn apẹẹrẹ ni o wa fun idi ti a fi gba imo Vediki bi oro Ọrọ Ọlọrun. Fun apẹẹrẹ, ni eyi ti o kan awon Hindu, bi won se gba imọ Vediki lati wa ni pipe, apẹẹrẹ kekere kan niyi. Fun apẹẹrẹ, igbẹ Maalu jẹ ti ẹya ẹranko. ati ni ibamu pẹlu smṛti, tabi ilana Vediki, ti eniyan ba fọwọkan igbẹ ẹranko o ni lati yara wẹ ki o fọ ara rẹ mọ. Sugbọn ninu iwe mimọ Vediki igbẹ Maalu ti wa ni kakun bi ohun èlo iwẹmimọ. Kàkà bẹẹ, ibi eleeri tabi ohun eleeri ti wa ni iwẹmọ nipa ifọwọkan igbẹ Maalu. Bayi ti eniyan ba njiyan pe bawo ni o se jẹ, ti ni oju kan ti a ti sọ wipe igbẹ ẹranko jẹ eleeri, ati nibo miiran ti a wi pe igbẹ maalu ti o tun jẹ igbẹ ẹya eranko, o jẹ kìki, eyi jẹ itakora. Sugbọn lootọ, o le dabi wipe wọn takora, sugbọn nitoripe o jẹ ilana Vediki, nitorina a ti gba bẹ fun iwulo. bẹ nitootọ ti eniyan ba gba eyi, ki ise aṣiṣe. O ti je awari nipa oloogun iwoyi, Imọ sayensi, Dr. Lal Mohan Gosal, o ti še itupalẹ finifini igbẹ Maalu o si ti ri ti fihàn pe igbẹ Maalu ni gbogbo ini-apakokoro. Nítorí náà, bakanna, o ti tun se atupale omi odo Ganga nipa iriidi. Nitorina ero mi niwipe imọ Vediki wa ni pipe nitori ti o ju gbogbo iyèméjì ati awọn ašiše, Bhagavad-gita si ni koko ti gbogbo imọ Vediki. imọ ilana Vediki jẹ Ọrọ Ọlọrun.O ti sọkalẹ wa nipasẹ pipe atọwọdọwọ awọn ọmọ lẹhin.

Nitorina Imọ Vediki ki se ọrọ iwadi. Iṣẹ iwadi wa jẹ áìsedédé nitori a nse iwadi awọn nkan pẹlu iye ori aláìpé. Nitorina ibajade iwaadi yi na kole daju, kosi bosele daju. . A ni lati gba imọ pipe ti o sọ kalẹ wa, bi o ti wa ni mẹnuba ninu Bhagavad-gita, gege bi a se bere, evaṁ paramparā-prāptam imaṁ rājarṣayo viduḥ (BG 4.2). A ni lati gba imọ lati orisun to tọ ni atọwọdọwọ awọn ọmọ lẹhin ti o ni bẹrẹ la ti ọdọ olukọni to gajulọ, Oluwa Funararẹ. awọn ọrọ Bhagavad-gita si ti ọdọ Oluwa Funara Rẹ wa. Ati Arjuna, mo lero lati wi, akẹkọ ti o gba ẹkọ Bhagavad-gītā lati ọdọ Oluwa Ọlọrun gbà ohun gbogbo ti O wi lai se ijiyan lai yo nkankan kuro. Ko se gbàlaaye lati gba ìpa kan ti Bhagavad Gita ki a si kọ miiran. Rara. A gbọdọ gba Bhagavad Gita lai fun ni itumọ, laisi piparẹ, ati laisi ikopa bi o ti wu wa ninu ọrọ na. nitoripe o yẹ ki a gbà bi igbejade ti imọ Vediki ti o wa ni pipe julọ. Imọ Vediki ti wa lati awọn orisun imọlẹ, awọn ọrọ akọkọ rẹ si ti ọdọ Oluwa Funara Rẹ wa. A npe ọrọ ti Oluwa sọ ni apauruṣeya, ti o tumọsi wipe nwọn jẹ ọrọ ti o yatọ si ọrọ ti eniyan ile aye ti o ti karun awọn abawọn mẹrin. Eniyan alafẹ aye ni alebu mẹrin ninu aye won, ti won jẹ 1) o daju pe o ni lati se ašiše, 2) o ma ni iruju nigba si gba, ati 3) o ni iwa lati yan ẹlomiran jẹ, ati 4) o ti ni idilọwọ nipa iye ori ti wọn wa laipe. Pẹlu awọn àìsedéde mẹrin wọnyi, ko si ẹni ti o le funni ni alaye pipe lori imọ ti o kari aye. Imọ ilana Vediki ko ri bẹ. Brahmā, ẹni akọda, ti gba lẹkọ ninu ọkan rẹ, Brahmā na si tun pin imọ yi fun awọn ọmọ rẹ ati awọn ọmọ-lẹhin rẹ, bi wọn ti gba ni atetekọse lati ọdọ Oluwa.